Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Jathiya Ayahs #21 Translated in Yoruba

وَآتَيْنَاهُمْ بَيِّنَاتٍ مِنَ الْأَمْرِ ۖ فَمَا اخْتَلَفُوا إِلَّا مِنْ بَعْدِ مَا جَاءَهُمُ الْعِلْمُ بَغْيًا بَيْنَهُمْ ۚ إِنَّ رَبَّكَ يَقْضِي بَيْنَهُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ فِيمَا كَانُوا فِيهِ يَخْتَلِفُونَ
A tun fun won ni awon eri t’o yanju nipa oro naa. Nitori naa, won ko pin si ijo otooto afi leyin ti imo (’Islam) de ba won. (Won se bee) nipase ote aarin won (si awon Anabi). Dajudaju Oluwa re l’O maa se idajo laaarin won ni Ojo Ajinde nipa nnkan ti won n yapa enu si
ثُمَّ جَعَلْنَاكَ عَلَىٰ شَرِيعَةٍ مِنَ الْأَمْرِ فَاتَّبِعْهَا وَلَا تَتَّبِعْ أَهْوَاءَ الَّذِينَ لَا يَعْلَمُونَ
Leyin naa, A fi o si oju ona kan ninu oro (esin ’Islam). Nitori naa, tele e. Ki o si ma se tele ife-inu awon ti ko nimo
إِنَّهُمْ لَنْ يُغْنُوا عَنْكَ مِنَ اللَّهِ شَيْئًا ۚ وَإِنَّ الظَّالِمِينَ بَعْضُهُمْ أَوْلِيَاءُ بَعْضٍ ۖ وَاللَّهُ وَلِيُّ الْمُتَّقِينَ
Dajudaju won ko le ro o loro kini kan nibi iya ni odo Allahu. Ati pe dajudaju awon alabosi, apa kan won lore apa kan. Allahu si ni Ore awon oluberu (Re)
هَٰذَا بَصَائِرُ لِلنَّاسِ وَهُدًى وَرَحْمَةٌ لِقَوْمٍ يُوقِنُونَ
Eyi ni itosona fun awon eniyan. Imona ati ike ni fun ijo t’o ni amodaju
أَمْ حَسِبَ الَّذِينَ اجْتَرَحُوا السَّيِّئَاتِ أَنْ نَجْعَلَهُمْ كَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ سَوَاءً مَحْيَاهُمْ وَمَمَاتُهُمْ ۚ سَاءَ مَا يَحْكُمُونَ
Tabi awon t’o n se ise aburu lero pe A maa se won gege bi (A ti se) awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, ki isemi aye won ati iku won ri bakan naa? Ohun ti won n da lejo buru

Choose other languages: