Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Isra Ayahs #71 Translated in Yoruba

وَإِذَا مَسَّكُمُ الضُّرُّ فِي الْبَحْرِ ضَلَّ مَنْ تَدْعُونَ إِلَّا إِيَّاهُ ۖ فَلَمَّا نَجَّاكُمْ إِلَى الْبَرِّ أَعْرَضْتُمْ ۚ وَكَانَ الْإِنْسَانُ كَفُورًا
Nigba ti inira ba fowo ba yin loju omi, eni ti e n pe yo si dofo (mo yin lowo) afi Oun nikan (Allahu). Nigba ti O ba si gba yin la (ti e) gunle, e n gbunri (kuro lodo Re). Eniyan si je alaimoore
أَفَأَمِنْتُمْ أَنْ يَخْسِفَ بِكُمْ جَانِبَ الْبَرِّ أَوْ يُرْسِلَ عَلَيْكُمْ حَاصِبًا ثُمَّ لَا تَجِدُوا لَكُمْ وَكِيلًا
Se e fokan bale pe (Allahu) ko le mu apa kan ile ri mo yin lese ni? Tabi pe ko le fi okuta ina ranse si yin? Leyin naa, e o si nii ri oluso kan ti o maa gba yin la
أَمْ أَمِنْتُمْ أَنْ يُعِيدَكُمْ فِيهِ تَارَةً أُخْرَىٰ فَيُرْسِلَ عَلَيْكُمْ قَاصِفًا مِنَ الرِّيحِ فَيُغْرِقَكُمْ بِمَا كَفَرْتُمْ ۙ ثُمَّ لَا تَجِدُوا لَكُمْ عَلَيْنَا بِهِ تَبِيعًا
Tabi e fokan bale pe (Allahu) ko nii pada mu yin wa si (ori omi) nigba miiran ni; ti O maa ran iji ategun si yin, ti O si maa te yin ri (sinu omi) nitori pe e sai moore? Leyin naa, e o si nii ri oluranlowo kan t’o maa ba yin gbesan lara Wa
وَلَقَدْ كَرَّمْنَا بَنِي آدَمَ وَحَمَلْنَاهُمْ فِي الْبَرِّ وَالْبَحْرِ وَرَزَقْنَاهُمْ مِنَ الطَّيِّبَاتِ وَفَضَّلْنَاهُمْ عَلَىٰ كَثِيرٍ مِمَّنْ خَلَقْنَا تَفْضِيلًا
Dajudaju A se aponle fun awon omo (Anabi) Adam; A gbe won rin lori ile ati lori omi; A fun won ni ije-imu ninu awon nnkan daadaa; A si soore ajulo fun won gan-an lori opolopo ninu awon ti A da
يَوْمَ نَدْعُو كُلَّ أُنَاسٍ بِإِمَامِهِمْ ۖ فَمَنْ أُوتِيَ كِتَابَهُ بِيَمِينِهِ فَأُولَٰئِكَ يَقْرَءُونَ كِتَابَهُمْ وَلَا يُظْلَمُونَ فَتِيلًا
Ni ojo ti A oo maa pe gbogbo eniyan pelu asiwaju won . Nigba naa, enikeni ti A ba fun ni iwe (ise) re ni owo otun re, awon wonyen ni won yoo maa ka iwe (ise) won. A o si nii sabosi bin-intin si won

Choose other languages: