Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Isra Ayahs #25 Translated in Yoruba

انْظُرْ كَيْفَ فَضَّلْنَا بَعْضَهُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ ۚ وَلَلْآخِرَةُ أَكْبَرُ دَرَجَاتٍ وَأَكْبَرُ تَفْضِيلًا
Wo bi A se fun apa kan won loore ajulo lori apa kan (nile aye). Dajudaju torun tun tobi julo ni ipo, o si tobi julo loore ajulo
لَا تَجْعَلْ مَعَ اللَّهِ إِلَٰهًا آخَرَ فَتَقْعُدَ مَذْمُومًا مَخْذُولًا
Ma se mu olohun miiran mo Allahu nitori ki o ma baa jokoo (sinu Ina) ni eni abuku, eni ti won maa da isoro re da
وَقَضَىٰ رَبُّكَ أَلَّا تَعْبُدُوا إِلَّا إِيَّاهُ وَبِالْوَالِدَيْنِ إِحْسَانًا ۚ إِمَّا يَبْلُغَنَّ عِنْدَكَ الْكِبَرَ أَحَدُهُمَا أَوْ كِلَاهُمَا فَلَا تَقُلْ لَهُمَا أُفٍّ وَلَا تَنْهَرْهُمَا وَقُلْ لَهُمَا قَوْلًا كَرِيمًا
Oluwa re pase pe: “E ma se josin fun eni kan ayafi Oun. Ki e si se daadaa si awon obi (yin) mejeeji. Ti okan ninu awon mejeeji tabi ikini keji won ba dagba si o lodo, ma se sio si won, ma se jagbe mo won. Maa ba awon mejeeji so oro aponle
وَاخْفِضْ لَهُمَا جَنَاحَ الذُّلِّ مِنَ الرَّحْمَةِ وَقُلْ رَبِّ ارْحَمْهُمَا كَمَا رَبَّيَانِي صَغِيرًا
Ki o si re apa re nile lati fi bowo fun awon mejeeji nipa sise aanu won. Ki o si so pe: "Oluwa Eledaa mi, ke awon mejeeji gege bi won se re mi ni kekere
رَبُّكُمْ أَعْلَمُ بِمَا فِي نُفُوسِكُمْ ۚ إِنْ تَكُونُوا صَالِحِينَ فَإِنَّهُ كَانَ لِلْأَوَّابِينَ غَفُورًا
Oluwa yin nimo julo nipa ohun ti n be ninu emi yin, ti e ba je eni rere. Dajudaju O n je Alaforijin fun awon oluronupiwada

Choose other languages: