Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Hujraat Ayahs #13 Translated in Yoruba

وَإِنْ طَائِفَتَانِ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ اقْتَتَلُوا فَأَصْلِحُوا بَيْنَهُمَا ۖ فَإِنْ بَغَتْ إِحْدَاهُمَا عَلَى الْأُخْرَىٰ فَقَاتِلُوا الَّتِي تَبْغِي حَتَّىٰ تَفِيءَ إِلَىٰ أَمْرِ اللَّهِ ۚ فَإِنْ فَاءَتْ فَأَصْلِحُوا بَيْنَهُمَا بِالْعَدْلِ وَأَقْسِطُوا ۖ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الْمُقْسِطِينَ
Ti igun meji ninu awon onigbagbo ododo ba n ba ara won ja, e se atunse laaarin awon mejeeji. Ti okan ninu awon mejeeji ba si koja enu-ala lori ikeji, e ba eyi ti o koja enu-ala ja titi o fi maa seri pada sibi ase Allahu. Ti o ba si seri pada, e se atunse laaarin awon mejeeji pelu deede. Ki e si se eto. Dajudaju Allahu feran awon oluse-eto
إِنَّمَا الْمُؤْمِنُونَ إِخْوَةٌ فَأَصْلِحُوا بَيْنَ أَخَوَيْكُمْ ۚ وَاتَّقُوا اللَّهَ لَعَلَّكُمْ تُرْحَمُونَ
Omo iya (esin) ni awon onigbagbo ododo. Nitori naa, e satunse laaarin awon omo iya yin mejeeji. Ki e si beru Allahu nitori ki A le ke yin
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا يَسْخَرْ قَوْمٌ مِنْ قَوْمٍ عَسَىٰ أَنْ يَكُونُوا خَيْرًا مِنْهُمْ وَلَا نِسَاءٌ مِنْ نِسَاءٍ عَسَىٰ أَنْ يَكُنَّ خَيْرًا مِنْهُنَّ ۖ وَلَا تَلْمِزُوا أَنْفُسَكُمْ وَلَا تَنَابَزُوا بِالْأَلْقَابِ ۖ بِئْسَ الِاسْمُ الْفُسُوقُ بَعْدَ الْإِيمَانِ ۚ وَمَنْ لَمْ يَتُبْ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الظَّالِمُونَ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, awon eniyan kan ko gbodo fi awon eniyan kan se yeye. O le je pe awon (ti won so di oniyeye) dara ju awon (t’o n se yeye). Awon obinrin kan (ko si gbodo fi) awon obinrin kan (se yeye). O le je pe awon (ti won so di oniyeye) dara ju awon (t’o n se yeye). E ma se bura yin. E ma pe’ra yin loriki buruku leyin igbagbo ododo. Enikeni ti ko ba ronu piwada, awon wonyen ni awon alabosi
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اجْتَنِبُوا كَثِيرًا مِنَ الظَّنِّ إِنَّ بَعْضَ الظَّنِّ إِثْمٌ ۖ وَلَا تَجَسَّسُوا وَلَا يَغْتَبْ بَعْضُكُمْ بَعْضًا ۚ أَيُحِبُّ أَحَدُكُمْ أَنْ يَأْكُلَ لَحْمَ أَخِيهِ مَيْتًا فَكَرِهْتُمُوهُ ۚ وَاتَّقُوا اللَّهَ ۚ إِنَّ اللَّهَ تَوَّابٌ رَحِيمٌ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e jinna si opolopo aroso. Dajudaju apa kan aroso ni ese. E ma se topinpin ara yin. Ki apa kan yin ma se soro apa kan leyin. Se okan ninu yin nifee si lati je eran-ara omo iya re t’o ti ku ni? E si korira re. E beru Allahu. Dajudaju Allahu ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun
يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنَّا خَلَقْنَاكُمْ مِنْ ذَكَرٍ وَأُنْثَىٰ وَجَعَلْنَاكُمْ شُعُوبًا وَقَبَائِلَ لِتَعَارَفُوا ۚ إِنَّ أَكْرَمَكُمْ عِنْدَ اللَّهِ أَتْقَاكُمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ عَلِيمٌ خَبِيرٌ
Eyin eniyan, dajudaju Awa seda yin lati ara okunrin ati obinrin. A si se yin ni orile-ede orile-ede ati iran-iran nitori ki e le dara yin mo. Dajudaju alapon-onle julo ninu yin lodo Allahu ni eni t’o beru (Re) julo. Dajudaju Allahu ni Onimo, Alamotan

Choose other languages: