Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Hijr Ayahs #29 Translated in Yoruba

وَإِنَّ رَبَّكَ هُوَ يَحْشُرُهُمْ ۚ إِنَّهُ حَكِيمٌ عَلِيمٌ
Dajudaju Oluwa re, Oun l’O maa ko won jo. Dajudaju Oun ni Ologbon, Onimo
وَلَقَدْ خَلَقْنَا الْإِنْسَانَ مِنْ صَلْصَالٍ مِنْ حَمَإٍ مَسْنُونٍ
Dajudaju A seda eniyan lati ara amo t’o n dun koko, t’o ti pawoda
وَالْجَانَّ خَلَقْنَاهُ مِنْ قَبْلُ مِنْ نَارِ السَّمُومِ
Ati pe alujannu, A seda re siwaju (eniyan) lati ara ina alategun gbigbona ti ko ni eefin
وَإِذْ قَالَ رَبُّكَ لِلْمَلَائِكَةِ إِنِّي خَالِقٌ بَشَرًا مِنْ صَلْصَالٍ مِنْ حَمَإٍ مَسْنُونٍ
(Ranti) nigba ti Oluwa re so fun awon molaika pe: “Dajudaju Emi yoo se eda abara kan lati ara amo t’o n dun koko, t’o ti pawoda
فَإِذَا سَوَّيْتُهُ وَنَفَخْتُ فِيهِ مِنْ رُوحِي فَقَعُوا لَهُ سَاجِدِينَ
Nigba ti Mo ba se e t’o gun rege tan, ti Mo fe emi si i (lara) ninu emi Mi (ti Mo da), nigba naa e doju bole fun un ni oluforikanle-kini

Choose other languages: