Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Hajj Ayahs #76 Translated in Yoruba

وَإِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِمْ آيَاتُنَا بَيِّنَاتٍ تَعْرِفُ فِي وُجُوهِ الَّذِينَ كَفَرُوا الْمُنْكَرَ ۖ يَكَادُونَ يَسْطُونَ بِالَّذِينَ يَتْلُونَ عَلَيْهِمْ آيَاتِنَا ۗ قُلْ أَفَأُنَبِّئُكُمْ بِشَرٍّ مِنْ ذَٰلِكُمُ ۗ النَّارُ وَعَدَهَا اللَّهُ الَّذِينَ كَفَرُوا ۖ وَبِئْسَ الْمَصِيرُ
Nigba ti won ba n ke awon ayah Wa t’o yanju fun won, o maa ri ikoro-oju ninu oju awon t’o sai gbagbo; won yo si fee fowo inira kan awon ti n ke awon ayah Wa fun won. So pe: "Se ki ng fun yin ni iro ohun t’o buru ju iyen? Ina ti Allahu seleri re fun awon t’o sai gbagbo ni. Ikangun naa si buru
يَا أَيُّهَا النَّاسُ ضُرِبَ مَثَلٌ فَاسْتَمِعُوا لَهُ ۚ إِنَّ الَّذِينَ تَدْعُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ لَنْ يَخْلُقُوا ذُبَابًا وَلَوِ اجْتَمَعُوا لَهُ ۖ وَإِنْ يَسْلُبْهُمُ الذُّبَابُ شَيْئًا لَا يَسْتَنْقِذُوهُ مِنْهُ ۚ ضَعُفَ الطَّالِبُ وَالْمَطْلُوبُ
Eyin eniyan, Won fi akawe kan lele. Nitori naa, e teti si i. Dajudaju awon ti e n pe leyin Allahu, won ko le da esinsin kan, won ibaa para po lati se bee. Ti esinsin ba si gba kini kan mo won lowo, won ko le gba a pada lowo re. Ole ni eni ti n wa nnkan (lodo orisa) ati (orisa) ti won n wa nnkan lodo re
مَا قَدَرُوا اللَّهَ حَقَّ قَدْرِهِ ۗ إِنَّ اللَّهَ لَقَوِيٌّ عَزِيزٌ
Won ko bu owo fun Allahu ni owo ti o to si I. Dajudaju Allahu ma ni Alagbara, Olubori
اللَّهُ يَصْطَفِي مِنَ الْمَلَائِكَةِ رُسُلًا وَمِنَ النَّاسِ ۚ إِنَّ اللَّهَ سَمِيعٌ بَصِيرٌ
Allahu l’O n sa awon kan lesa (lati je) Ojise ninu awon molaika ati ninu awon eniyan. Dajudaju Allahu ni Olugbo, Oluriran
يَعْلَمُ مَا بَيْنَ أَيْدِيهِمْ وَمَا خَلْفَهُمْ ۗ وَإِلَى اللَّهِ تُرْجَعُ الْأُمُورُ
O mo ohun ti n be niwaju won ati ni eyin won. Odo Allahu si ni won maa seri awon oro eda pada si

Choose other languages: