Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Hajj Ayahs #51 Translated in Yoruba

وَيَسْتَعْجِلُونَكَ بِالْعَذَابِ وَلَنْ يُخْلِفَ اللَّهُ وَعْدَهُ ۚ وَإِنَّ يَوْمًا عِنْدَ رَبِّكَ كَأَلْفِ سَنَةٍ مِمَّا تَعُدُّونَ
Won si n kan o loju fun iya naa. Allahu ko si nii yapa adehun Re. Dajudaju ojo kan lodo Oluwa re da bi egberun odun ninu ohun ti e n ka (ni onka). Allahu (subhanahu wa ta’ala) n so nipa idi ti iya ko fi tete sokale le awon alaigbagbo lori pe ti Oun ba so fun won pe aaro ola ni ojo iya won (bi apeere) dipo egberun odun. Kiye si i ninu ayah ojo kan elegberun odun o tun le je oke meji aabo odun yala nile yii tabi lojo Ajinde
وَكَأَيِّنْ مِنْ قَرْيَةٍ أَمْلَيْتُ لَهَا وَهِيَ ظَالِمَةٌ ثُمَّ أَخَذْتُهَا وَإِلَيَّ الْمَصِيرُ
Meloo meloo ninu ilu ti Mo lo lara, ti won je alabosi. Leyin naa, Mo gba won mu. Odo Mi si ni abo eda
قُلْ يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنَّمَا أَنَا لَكُمْ نَذِيرٌ مُبِينٌ
So pe: "Eyin eniyan, emi ma ni olukilo ponnbele fun yin
فَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَهُمْ مَغْفِرَةٌ وَرِزْقٌ كَرِيمٌ
Nitori naa, awon t’o ba gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere, aforijin ati arisiki alapon-onle n be fun won
وَالَّذِينَ سَعَوْا فِي آيَاتِنَا مُعَاجِزِينَ أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ الْجَحِيمِ
Awon t’o se ise buruku nipa awon ayah Wa, (ti won lero pe) awon mori bo ninu iya; awon wonyen ni ero inu ina Jehim

Choose other languages: