Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Hadid Ayahs #29 Translated in Yoruba

ثُمَّ قَفَّيْنَا عَلَىٰ آثَارِهِمْ بِرُسُلِنَا وَقَفَّيْنَا بِعِيسَى ابْنِ مَرْيَمَ وَآتَيْنَاهُ الْإِنْجِيلَ وَجَعَلْنَا فِي قُلُوبِ الَّذِينَ اتَّبَعُوهُ رَأْفَةً وَرَحْمَةً وَرَهْبَانِيَّةً ابْتَدَعُوهَا مَا كَتَبْنَاهَا عَلَيْهِمْ إِلَّا ابْتِغَاءَ رِضْوَانِ اللَّهِ فَمَا رَعَوْهَا حَقَّ رِعَايَتِهَا ۖ فَآتَيْنَا الَّذِينَ آمَنُوا مِنْهُمْ أَجْرَهُمْ ۖ وَكَثِيرٌ مِنْهُمْ فَاسِقُونَ
Leyin naa, A fi awon Ojise Wa tele oripa won. A si mu ‘Isa omo Moryam tele won. A fun un ni al-’Injil. A fi aanu ati ike sinu okan awon t’o tele e. Asa adawa (lai loko tabi lai laya) won se adadaale re ni. A o se e ni oran-anyan le won lori. (Won ko si se adawa fun kini kan) bi ko se lati fi wa iyonu Allahu. Won ko si ri i so bi o se ye ki won so o. Nitori naa, A fun awon t’o gbagbo ni ododo ninu won ni esan won. Opolopo ninu won si ni obileje
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اتَّقُوا اللَّهَ وَآمِنُوا بِرَسُولِهِ يُؤْتِكُمْ كِفْلَيْنِ مِنْ رَحْمَتِهِ وَيَجْعَلْ لَكُمْ نُورًا تَمْشُونَ بِهِ وَيَغْفِرْ لَكُمْ ۚ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَحِيمٌ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e beru Allahu, ki e si gba Ojise Re gbo ni ododo, nitori ki (Allahu) le fun yin ni ilopo meji ninu ike Re ati nitori ki O le fun yin ni imole ti e oo maa fi rin ati nitori ki O le fori jin yin. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun
لِئَلَّا يَعْلَمَ أَهْلُ الْكِتَابِ أَلَّا يَقْدِرُونَ عَلَىٰ شَيْءٍ مِنْ فَضْلِ اللَّهِ ۙ وَأَنَّ الْفَضْلَ بِيَدِ اللَّهِ يُؤْتِيهِ مَنْ يَشَاءُ ۚ وَاللَّهُ ذُو الْفَضْلِ الْعَظِيمِ
(Allahu se bee fun yin) nitori ki awon ahlu-l-kitab le mo pe awon ko ni agbara lori kini kan ninu oore ajulo Allahu. Ati pe dajudaju oore ajulo, owo Allahu l’o wa. O si n fun eni ti O ba fe. Allahu si ni Oloore nla

Choose other languages: