Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Hadid Ayahs #4 Translated in Yoruba

سَبَّحَ لِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile n safomo fun Allahu. Oun si ni Alagbara, Ologbon
لَهُ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ يُحْيِي وَيُمِيتُ ۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
TiRe ni ijoba awon sanmo ati ile. O n so eda di alaaye. O si n so eda di oku. Oun ni Alagbara lori gbogbo nnkan
هُوَ الْأَوَّلُ وَالْآخِرُ وَالظَّاهِرُ وَالْبَاطِنُ ۖ وَهُوَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ
Oun ni Akoko ati Ikeyin. O han (pelu ami bibe Re). O si pamo (fun gbogbo oju nile aye). Oun ni Onimo nipa gbogbo nnkan
هُوَ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٍ ثُمَّ اسْتَوَىٰ عَلَى الْعَرْشِ ۚ يَعْلَمُ مَا يَلِجُ فِي الْأَرْضِ وَمَا يَخْرُجُ مِنْهَا وَمَا يَنْزِلُ مِنَ السَّمَاءِ وَمَا يَعْرُجُ فِيهَا ۖ وَهُوَ مَعَكُمْ أَيْنَ مَا كُنْتُمْ ۚ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ
Oun ni Eni ti O seda awon sanmo ati ile fun ojo mefa. Leyin naa, O gunwa si ori Ite-ola. O mo nnkan t’o n wo inu ile ati nnkan t’o n jade lati inu re, ati nnkan t’o n sokale lati inu sanmo ati nnkan t’o n gunke sinu re. Ati pe O wa pelu yin ni ibikibi ti e ba wa (pelu imo Re). Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise

Choose other languages: