Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #96 Translated in Yoruba

وَلَقَدْ جَاءَكُمْ مُوسَىٰ بِالْبَيِّنَاتِ ثُمَّ اتَّخَذْتُمُ الْعِجْلَ مِنْ بَعْدِهِ وَأَنْتُمْ ظَالِمُونَ
Ati pe dajudaju (Anabi) Musa ti mu awon eri t’o yanju wa ba yin. Leyin naa, e tun bo oborogidi omo maalu leyin re. Alabosi si ni yin.”
وَإِذْ أَخَذْنَا مِيثَاقَكُمْ وَرَفَعْنَا فَوْقَكُمُ الطُّورَ خُذُوا مَا آتَيْنَاكُمْ بِقُوَّةٍ وَاسْمَعُوا ۖ قَالُوا سَمِعْنَا وَعَصَيْنَا وَأُشْرِبُوا فِي قُلُوبِهِمُ الْعِجْلَ بِكُفْرِهِمْ ۚ قُلْ بِئْسَمَا يَأْمُرُكُمْ بِهِ إِيمَانُكُمْ إِنْ كُنْتُمْ مُؤْمِنِينَ
(E ranti) nigba ti A gba adehun lowo yin, A si gbe apata s’oke ori yin, (A so pe:) "E gba ohun ti A fun yin mu daradara. Ki e si teti gboro." Won wi pe: "A gbo (ase), a si yapa (ase)." Won ti ko ife bibo oborogidi omo maalu sinu okan won nipase aigbagbo won. So pe: "Aburu ni ohun ti igbagbo (iborisa) yin n pa yin lase re, ti e ba je onigbagbo ododo
قُلْ إِنْ كَانَتْ لَكُمُ الدَّارُ الْآخِرَةُ عِنْدَ اللَّهِ خَالِصَةً مِنْ دُونِ النَّاسِ فَتَمَنَّوُا الْمَوْتَ إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ
So pe: “Ti o ba je pe tiyin nikan ni Ile Ikeyin ti n be ni odo Allahu, ti ko si nii je ti awon eniyan (miiran), e toro iku, ti e ba je olododo
وَلَنْ يَتَمَنَّوْهُ أَبَدًا بِمَا قَدَّمَتْ أَيْدِيهِمْ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ بِالظَّالِمِينَ
Won ko nii toro iku laelae nitori ohun ti owo won ti siwaju. Allahu si ni Onimo nipa awon alabosi
وَلَتَجِدَنَّهُمْ أَحْرَصَ النَّاسِ عَلَىٰ حَيَاةٍ وَمِنَ الَّذِينَ أَشْرَكُوا ۚ يَوَدُّ أَحَدُهُمْ لَوْ يُعَمَّرُ أَلْفَ سَنَةٍ وَمَا هُوَ بِمُزَحْزِحِهِ مِنَ الْعَذَابِ أَنْ يُعَمَّرَ ۗ وَاللَّهُ بَصِيرٌ بِمَا يَعْمَلُونَ
Dajudaju o maa ri won pe awon ni eniyan t’o l’oju kokoro julo nipa isemi aye, (won tun l’oju kokoro ju) awon osebo lo. Ikookan won n fe pe ti A ba le fun oun ni egberun odun lo laye. Bee si ni, ki i se ohun ti o maa la a ninu iya ni pe ki A fun un ni isemi gigun lo. Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti won n se nise

Choose other languages: