Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #89 Translated in Yoruba

ثُمَّ أَنْتُمْ هَٰؤُلَاءِ تَقْتُلُونَ أَنْفُسَكُمْ وَتُخْرِجُونَ فَرِيقًا مِنْكُمْ مِنْ دِيَارِهِمْ تَظَاهَرُونَ عَلَيْهِمْ بِالْإِثْمِ وَالْعُدْوَانِ وَإِنْ يَأْتُوكُمْ أُسَارَىٰ تُفَادُوهُمْ وَهُوَ مُحَرَّمٌ عَلَيْكُمْ إِخْرَاجُهُمْ ۚ أَفَتُؤْمِنُونَ بِبَعْضِ الْكِتَابِ وَتَكْفُرُونَ بِبَعْضٍ ۚ فَمَا جَزَاءُ مَنْ يَفْعَلُ ذَٰلِكَ مِنْكُمْ إِلَّا خِزْيٌ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۖ وَيَوْمَ الْقِيَامَةِ يُرَدُّونَ إِلَىٰ أَشَدِّ الْعَذَابِ ۗ وَمَا اللَّهُ بِغَافِلٍ عَمَّا تَعْمَلُونَ
Leyin naa, eyin wonyi l’e n p’ara yin. E tun n le apa kan ninu yin jade kuro ninu ile won. E n fi ese ati abosi seranwo (fun awon ota) lori won. Ti won ba si wa ba yin (ti won ti di) eru, eyin n ra won (lati fi’ra yin seru). Eewo si feekan ni fun yin lati le won jade. Se eyin yoo gba apa kan Tira gbo, e si n sai gbagbo ninu apa kan? Nitori naa, ki ni esan fun eni to se yen ninu yin bi ko se abuku ninu isemi aye. Ni ojo Ajinde, won si maa da won pada sinu iya to le julo. Allahu ko si nii gbagbe ohun ti e n se nise
أُولَٰئِكَ الَّذِينَ اشْتَرَوُا الْحَيَاةَ الدُّنْيَا بِالْآخِرَةِ ۖ فَلَا يُخَفَّفُ عَنْهُمُ الْعَذَابُ وَلَا هُمْ يُنْصَرُونَ
Awon wonyen ni awon ti won fi orun ra isemi aye. Nitori naa, A o nii gbe iya fuye fun won, A o si nii ran won lowo
وَلَقَدْ آتَيْنَا مُوسَى الْكِتَابَ وَقَفَّيْنَا مِنْ بَعْدِهِ بِالرُّسُلِ ۖ وَآتَيْنَا عِيسَى ابْنَ مَرْيَمَ الْبَيِّنَاتِ وَأَيَّدْنَاهُ بِرُوحِ الْقُدُسِ ۗ أَفَكُلَّمَا جَاءَكُمْ رَسُولٌ بِمَا لَا تَهْوَىٰ أَنْفُسُكُمُ اسْتَكْبَرْتُمْ فَفَرِيقًا كَذَّبْتُمْ وَفَرِيقًا تَقْتُلُونَ
Dajudaju A ti fun (Anabi) Musa ni Tira. A si mu awon Ojise wa ni telentele leyin re. A tun fun (Anabi) ‘Isa omo Moryam ni awon eri t’o yanju. A tun fun ni agbara nipase Emi Mimo (iyen, Molaika Jibril). Se gbogbo igba ti Ojise kan ba wa ba yin pelu ohun ti okan yin ko fe ni e o maa segberaga? E si pe apa kan (awon Anabi) ni opuro, e si n pa apa kan
وَقَالُوا قُلُوبُنَا غُلْفٌ ۚ بَلْ لَعَنَهُمُ اللَّهُ بِكُفْرِهِمْ فَقَلِيلًا مَا يُؤْمِنُونَ
Won si wi pe: “Ebibo bo wa lokan.” Ko si ri bee. Allahu ti sebi le won ni nitori aigbagbo won. Sebi die ni won n gbagbo
وَلَمَّا جَاءَهُمْ كِتَابٌ مِنْ عِنْدِ اللَّهِ مُصَدِّقٌ لِمَا مَعَهُمْ وَكَانُوا مِنْ قَبْلُ يَسْتَفْتِحُونَ عَلَى الَّذِينَ كَفَرُوا فَلَمَّا جَاءَهُمْ مَا عَرَفُوا كَفَرُوا بِهِ ۚ فَلَعْنَةُ اللَّهِ عَلَى الْكَافِرِينَ
Nigba ti Tira kan si de ba won lati odo Allahu, ti o n fi idi ododo mule nipa ohun ti o wa pelu won, bee si ni teletele won ti n toro isegun lori awon to sai gbagbo, amo nigba ti ohun ti won nimo nipa re de ba won, won sai gbagbo ninu re. Nitori naa, ibi dandan Allahu ki o maa ba awon alaigbagbo

Choose other languages: