Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #31 Translated in Yoruba

الَّذِينَ يَنْقُضُونَ عَهْدَ اللَّهِ مِنْ بَعْدِ مِيثَاقِهِ وَيَقْطَعُونَ مَا أَمَرَ اللَّهُ بِهِ أَنْ يُوصَلَ وَيُفْسِدُونَ فِي الْأَرْضِ ۚ أُولَٰئِكَ هُمُ الْخَاسِرُونَ
Awon t’o n ye majemu Allahu leyin ti majemu naa ti fidi mule, won tun n ja ohun ti Allahu pa lase pe ki won dapo, won si n se ibaje lori ile, awon wonyen gan-an ni eni ofo
كَيْفَ تَكْفُرُونَ بِاللَّهِ وَكُنْتُمْ أَمْوَاتًا فَأَحْيَاكُمْ ۖ ثُمَّ يُمِيتُكُمْ ثُمَّ يُحْيِيكُمْ ثُمَّ إِلَيْهِ تُرْجَعُونَ
Bawo ni e se n sai gbagbo ninu Allahu na! Bee si ni oku ni yin (tele), O si so yin di alaaye. Leyin naa, O maa so yin di oku. Leyin naa, O maa so yin di alaaye. Leyin naa, odo Re ni won yoo da yin pada si
هُوَ الَّذِي خَلَقَ لَكُمْ مَا فِي الْأَرْضِ جَمِيعًا ثُمَّ اسْتَوَىٰ إِلَى السَّمَاءِ فَسَوَّاهُنَّ سَبْعَ سَمَاوَاتٍ ۚ وَهُوَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ
Oun ni Eni ti O da ohunkohun t’o wa lori ile fun yin patapata. Leyin naa, O wa l’oke sanmo, O si se won togun rege si sanmo meje. Oun si ni Onimo nipa gbogbo nnkan
وَإِذْ قَالَ رَبُّكَ لِلْمَلَائِكَةِ إِنِّي جَاعِلٌ فِي الْأَرْضِ خَلِيفَةً ۖ قَالُوا أَتَجْعَلُ فِيهَا مَنْ يُفْسِدُ فِيهَا وَيَسْفِكُ الدِّمَاءَ وَنَحْنُ نُسَبِّحُ بِحَمْدِكَ وَنُقَدِّسُ لَكَ ۖ قَالَ إِنِّي أَعْلَمُ مَا لَا تَعْلَمُونَ
iseda ile siwaju iseda sanmo gege bi ayah inu surah Baƙorah yen se fi rinle. Amo ki i se oro nipa iseda ile ni ayah surah an-Nazi‘at n soro nipa re. Allahu (subhanahu wa ta’ala) ko si lo oro t’o tumo si iseda ile ninu ayah t’O ti daruko ile iyen ayah 30 ninu surah iseda gbogbo ohun t’o maa wa ninu ile ni awon igi awon ibudo 30 (Ranti) nigba ti Oluwa re so fun awon molaika pe: “Dajudaju Emi yoo fi arole kan sori ile.” Won so pe: “Se Iwo yoo fi eni ti o maa sebaje sibe, ti o si maa teje sile? Awa si n se afomo pelu idupe fun O. A si n fi ogo fun O!" O so pe: “Dajudaju Emi mo ohun ti eyin ko mo.”
وَعَلَّمَ آدَمَ الْأَسْمَاءَ كُلَّهَا ثُمَّ عَرَضَهُمْ عَلَى الْمَلَائِكَةِ فَقَالَ أَنْبِئُونِي بِأَسْمَاءِ هَٰؤُلَاءِ إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ
Allahu fi awon oruko naa, gbogbo won patapata, mo Adam. Leyin naa, O ko won siwaju awon molaika, O si so pe: “E so awon oruko wonyi fun Mi, ti e ba je olododo.”

Choose other languages: