Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #276 Translated in Yoruba

لَيْسَ عَلَيْكَ هُدَاهُمْ وَلَٰكِنَّ اللَّهَ يَهْدِي مَنْ يَشَاءُ ۗ وَمَا تُنْفِقُوا مِنْ خَيْرٍ فَلِأَنْفُسِكُمْ ۚ وَمَا تُنْفِقُونَ إِلَّا ابْتِغَاءَ وَجْهِ اللَّهِ ۚ وَمَا تُنْفِقُوا مِنْ خَيْرٍ يُوَفَّ إِلَيْكُمْ وَأَنْتُمْ لَا تُظْلَمُونَ
Imona won ko si lorun re, sugbon Allahu l’O n fi eni ti O ba fe mona. Ohunkohun ti e ba n na ni ohun rere, fun emi ara yin ni. E o si nii nawo afi lati fi wa oju rere Allahu. Ohunkohun ti e ba si na ni ohun rere, A o san yin ni esan (re) ni ekun-rere. Won ko si nii sabosi si yin
لِلْفُقَرَاءِ الَّذِينَ أُحْصِرُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ لَا يَسْتَطِيعُونَ ضَرْبًا فِي الْأَرْضِ يَحْسَبُهُمُ الْجَاهِلُ أَغْنِيَاءَ مِنَ التَّعَفُّفِ تَعْرِفُهُمْ بِسِيمَاهُمْ لَا يَسْأَلُونَ النَّاسَ إِلْحَافًا ۗ وَمَا تُنْفِقُوا مِنْ خَيْرٍ فَإِنَّ اللَّهَ بِهِ عَلِيمٌ
(E tore) fun awon alaini ti won se (ara won monu mosalasi Anabi nitori ki won le maa jagun) fun aabo esin Allahu. Won ko si lagbara lilo-bibo lori ile (fun okowo sise). Eni ti ko mo won maa ka won kun oloro latara aisagbe. O maa mo won pelu ami won. Won ko nii toro nnkan lowo eniyan lemolemo. Ohunkohun ti e ba na ni ohun rere, dajudaju Allahu ni Onimo nipa re
الَّذِينَ يُنْفِقُونَ أَمْوَالَهُمْ بِاللَّيْلِ وَالنَّهَارِ سِرًّا وَعَلَانِيَةً فَلَهُمْ أَجْرُهُمْ عِنْدَ رَبِّهِمْ وَلَا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ
Awon t’o n na owo won ni oru ati ni osan, ni ikoko ati ni gbangba, esan won n be fun won ni odo Oluwa won. Ko si ipaya fun won. Won ko si nii banuje
الَّذِينَ يَأْكُلُونَ الرِّبَا لَا يَقُومُونَ إِلَّا كَمَا يَقُومُ الَّذِي يَتَخَبَّطُهُ الشَّيْطَانُ مِنَ الْمَسِّ ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ قَالُوا إِنَّمَا الْبَيْعُ مِثْلُ الرِّبَا ۗ وَأَحَلَّ اللَّهُ الْبَيْعَ وَحَرَّمَ الرِّبَا ۚ فَمَنْ جَاءَهُ مَوْعِظَةٌ مِنْ رَبِّهِ فَانْتَهَىٰ فَلَهُ مَا سَلَفَ وَأَمْرُهُ إِلَى اللَّهِ ۖ وَمَنْ عَادَ فَأُولَٰئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ ۖ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ
Awon t’o n je ele ko nii dide (ninu saree) afi bi eni ti Esu fowo ba ti n ta geegee yo se dide. Iyen ri bee nitori pe won wi pe: “Owo sise da bi owo ele.” Allahu si se owo sise ni eto, O si se owo ele ni eewo. Enikeni ti waasi ba de ba lati odo Oluwa re, ti o si jawo, tire ni eyi t’o siwaju, oro re si di odo Allahu. Enikeni ti o ba si pada (sibi owo ele), awon wonyen ni ero inu Ina. Olusegbere si ni won ninu re
يَمْحَقُ اللَّهُ الرِّبَا وَيُرْبِي الصَّدَقَاتِ ۗ وَاللَّهُ لَا يُحِبُّ كُلَّ كَفَّارٍ أَثِيمٍ
Allahu maa run owo ele. O si maa bu si awon ore. Allahu ko nifee gbogbo alaigbagbo, elese

Choose other languages: