Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #188 Translated in Yoruba

أَيَّامًا مَعْدُودَاتٍ ۚ فَمَنْ كَانَ مِنْكُمْ مَرِيضًا أَوْ عَلَىٰ سَفَرٍ فَعِدَّةٌ مِنْ أَيَّامٍ أُخَرَ ۚ وَعَلَى الَّذِينَ يُطِيقُونَهُ فِدْيَةٌ طَعَامُ مِسْكِينٍ ۖ فَمَنْ تَطَوَّعَ خَيْرًا فَهُوَ خَيْرٌ لَهُ ۚ وَأَنْ تَصُومُوا خَيْرٌ لَكُمْ ۖ إِنْ كُنْتُمْ تَعْلَمُونَ
(E gba aawe naa) fun awon ojo ti o ni onka. (Sugbon) enikeni ninu yin ti o ba je alaisan, tabi o wa lori irin-ajo, (o maa san) onka (gbese aawe re) ni awon ojo miiran. Ati pe itanran (iyen) fifun mekunnu ni ounje l’o di dandan fun awon t’o maa fi inira gba aawe. Enikeni ti o ba finnufindo se (alekun) ise oloore, o kuku loore julo fun un. Ati pe ki e gba aawe loore julo fun yin ti e ba mo
شَهْرُ رَمَضَانَ الَّذِي أُنْزِلَ فِيهِ الْقُرْآنُ هُدًى لِلنَّاسِ وَبَيِّنَاتٍ مِنَ الْهُدَىٰ وَالْفُرْقَانِ ۚ فَمَنْ شَهِدَ مِنْكُمُ الشَّهْرَ فَلْيَصُمْهُ ۖ وَمَنْ كَانَ مَرِيضًا أَوْ عَلَىٰ سَفَرٍ فَعِدَّةٌ مِنْ أَيَّامٍ أُخَرَ ۗ يُرِيدُ اللَّهُ بِكُمُ الْيُسْرَ وَلَا يُرِيدُ بِكُمُ الْعُسْرَ وَلِتُكْمِلُوا الْعِدَّةَ وَلِتُكَبِّرُوا اللَّهَ عَلَىٰ مَا هَدَاكُمْ وَلَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ
Osu Romodon eyi ti A so al-Ƙur’an kale ninu re 1 (ti o je) imona, awon alaye ponnbele nipa imona ati oro-ipinya 2 fun awon eniyan; nitori naa, enikeni ti o ba wa ninu ilu re ninu yin ninu osu naa, 3 ki o gba aawe osu naa. Enikeni ti o ba je alaisan tabi ti o ba wa lori irin-ajo, (o maa san) onka (gbese aawe re) ni awon ojo miiran. Allahu fe irorun fun yin, ko si fe inira fun yin. E pe onka (ojo aawe), ki e si gbe titobi fun Allahu nitori pe O fi ona mo yin ati nitori ki e le dupe fun Un. aye kan naa ni oke ‘Arafah wa sugbon ko pon dandan ki gbogbo aye bere aawe Romodon ni ojo kan naa ti a ba fe ki ojo ibere aawe Romodon wa ati ipari re maa je ojo kan naa gege bi o se pon dandan bee ninu ofin ’Islam a bukata si nnkan meji gbooro. Ikini: asiwaju eyo kan soso ti o maa je onisunnah
وَإِذَا سَأَلَكَ عِبَادِي عَنِّي فَإِنِّي قَرِيبٌ ۖ أُجِيبُ دَعْوَةَ الدَّاعِ إِذَا دَعَانِ ۖ فَلْيَسْتَجِيبُوا لِي وَلْيُؤْمِنُوا بِي لَعَلَّهُمْ يَرْشُدُونَ
Nigba ti awon erusin Mi ba bi o leere nipa Mi, dajudaju Emi ni Olusunmo. Emi yoo jepe adua aladuua nigba ti o ba pe Mi. Ki won je’pe Mi (nipa itele ase Mi). Ki won si gba Mi gbo nitori ki won le mona (gbigba adua)
أُحِلَّ لَكُمْ لَيْلَةَ الصِّيَامِ الرَّفَثُ إِلَىٰ نِسَائِكُمْ ۚ هُنَّ لِبَاسٌ لَكُمْ وَأَنْتُمْ لِبَاسٌ لَهُنَّ ۗ عَلِمَ اللَّهُ أَنَّكُمْ كُنْتُمْ تَخْتَانُونَ أَنْفُسَكُمْ فَتَابَ عَلَيْكُمْ وَعَفَا عَنْكُمْ ۖ فَالْآنَ بَاشِرُوهُنَّ وَابْتَغُوا مَا كَتَبَ اللَّهُ لَكُمْ ۚ وَكُلُوا وَاشْرَبُوا حَتَّىٰ يَتَبَيَّنَ لَكُمُ الْخَيْطُ الْأَبْيَضُ مِنَ الْخَيْطِ الْأَسْوَدِ مِنَ الْفَجْرِ ۖ ثُمَّ أَتِمُّوا الصِّيَامَ إِلَى اللَّيْلِ ۚ وَلَا تُبَاشِرُوهُنَّ وَأَنْتُمْ عَاكِفُونَ فِي الْمَسَاجِدِ ۗ تِلْكَ حُدُودُ اللَّهِ فَلَا تَقْرَبُوهَا ۗ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ اللَّهُ آيَاتِهِ لِلنَّاسِ لَعَلَّهُمْ يَتَّقُونَ
Won se ale aawe ni eto fun yin lati sunmo awon iyawo yin; awon ni aso yin, eyin si ni aso won. Allahu mo pe dajudaju e n tan ara yin je (nipa aife sun oorun ife ni ale aawe). O ti gba ironupiwada yin, O si se amojukuro fun yin. Ni bayii, e sunmo won, ki e si wa ohun ti Allahu ko mo yin (ni omo). E je, e mu titi e o fi ri iyato laaarin owu funfun (iyen, imole owuro) ati owu dudu (iyen, okunkun oru) ni afemojumo. Leyin naa, e pari aawe naa si ale (nigba ti oorun ba wo). E ma se sunmo won nigba ti e ba n kora ro ninu awon mosalasi. Iwonyen ni awon enu-ala (ti) Allahu (gbekale), e ma se sunmo on. Bayen ni Allahu se n salaye awon ayah Re fun awon eniyan nitori ki won le beru (Re)
وَلَا تَأْكُلُوا أَمْوَالَكُمْ بَيْنَكُمْ بِالْبَاطِلِ وَتُدْلُوا بِهَا إِلَى الْحُكَّامِ لِتَأْكُلُوا فَرِيقًا مِنْ أَمْوَالِ النَّاسِ بِالْإِثْمِ وَأَنْتُمْ تَعْلَمُونَ
Eyin ko gbodo fi eru je dukia yin laaarin ara yin. Eyin ko si gbodo gbe dukia lo ba awon adajo (ni abetele) nitori ki e le fi ese je ipin kan ninu dukia awon eniyan, eyin si mo

Choose other languages: