Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Araf Ayahs #74 Translated in Yoruba

قَالُوا أَجِئْتَنَا لِنَعْبُدَ اللَّهَ وَحْدَهُ وَنَذَرَ مَا كَانَ يَعْبُدُ آبَاؤُنَا ۖ فَأْتِنَا بِمَا تَعِدُنَا إِنْ كُنْتَ مِنَ الصَّادِقِينَ
Won wi pe: “Se o wa ba wa nitori ki a le josin fun Allahu nikan soso ati nitori ki a le pa ohun ti awon baba nla wa n josin fun ti? Nitori naa, mu ohun ti o se ni ileri fun wa se ti o ba wa ninu awon olododo.”
قَالَ قَدْ وَقَعَ عَلَيْكُمْ مِنْ رَبِّكُمْ رِجْسٌ وَغَضَبٌ ۖ أَتُجَادِلُونَنِي فِي أَسْمَاءٍ سَمَّيْتُمُوهَا أَنْتُمْ وَآبَاؤُكُمْ مَا نَزَّلَ اللَّهُ بِهَا مِنْ سُلْطَانٍ ۚ فَانْتَظِرُوا إِنِّي مَعَكُمْ مِنَ الْمُنْتَظِرِينَ
O so pe: “Iya ati ibinu kuku ti sokale sori yin lati odo Oluwa yin. Se e oo maa ja mi niyan nipa awon oruko (orisa) kan ti eyin ati awon baba yin fun loruko - Allahu ko si so eri kan kale fun un? – Nitori naa, e maa reti, dajudaju emi naa wa pelu yin ninu awon olureti.”
فَأَنْجَيْنَاهُ وَالَّذِينَ مَعَهُ بِرَحْمَةٍ مِنَّا وَقَطَعْنَا دَابِرَ الَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا ۖ وَمَا كَانُوا مُؤْمِنِينَ
Nitori naa, pelu aanu lati odo Wa, A gba oun ati awon t’o wa pelu re la. A si pa awon t’o pe awon ayah Wa niro run; won ki i se onigbagbo ododo
وَإِلَىٰ ثَمُودَ أَخَاهُمْ صَالِحًا ۗ قَالَ يَا قَوْمِ اعْبُدُوا اللَّهَ مَا لَكُمْ مِنْ إِلَٰهٍ غَيْرُهُ ۖ قَدْ جَاءَتْكُمْ بَيِّنَةٌ مِنْ رَبِّكُمْ ۖ هَٰذِهِ نَاقَةُ اللَّهِ لَكُمْ آيَةً ۖ فَذَرُوهَا تَأْكُلْ فِي أَرْضِ اللَّهِ ۖ وَلَا تَمَسُّوهَا بِسُوءٍ فَيَأْخُذَكُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ
A tun ran (eni kan) si awon iran Thamud, arakunrin won, Solih. O so pe: "Eyin ijo mi, e josin fun Allahu. E e ni olohun miiran leyin Re. Ise iyanu kuku ti de ba yin lati odo Oluwa yin; eyi ni abo rakunmi Allahu. (O je) ami kan fun yin. Nitori naa, e fi sile, ki o maa je kiri lori ile Allahu. E ma se fi owo aburu kan an nitori ki iya eleta-elero ma baa je yin
وَاذْكُرُوا إِذْ جَعَلَكُمْ خُلَفَاءَ مِنْ بَعْدِ عَادٍ وَبَوَّأَكُمْ فِي الْأَرْضِ تَتَّخِذُونَ مِنْ سُهُولِهَا قُصُورًا وَتَنْحِتُونَ الْجِبَالَ بُيُوتًا ۖ فَاذْكُرُوا آلَاءَ اللَّهِ وَلَا تَعْثَوْا فِي الْأَرْضِ مُفْسِدِينَ
E tun ranti nigba ti (Allahu) se yin ni arole leyin awon ara ‘Ad. O si fun yin ni ile igbe lori ile; e n ko ile nlanla sinu petele, e si n gbe awon ile sinu apata. E ranti awon idera Allahu, ki e si ma se rin lori ile ni ti obileje

Choose other languages: