Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Araf Ayahs #54 Translated in Yoruba

وَنَادَىٰ أَصْحَابُ النَّارِ أَصْحَابَ الْجَنَّةِ أَنْ أَفِيضُوا عَلَيْنَا مِنَ الْمَاءِ أَوْ مِمَّا رَزَقَكُمُ اللَّهُ ۚ قَالُوا إِنَّ اللَّهَ حَرَّمَهُمَا عَلَى الْكَافِرِينَ
Ero inu Ina yoo pe ero inu Ogba Idera pe: “E fun wa ninu omi tabi ninu ohun ti Allahu pa lese fun yin.” Won yoo so pe: “Dajudaju Allahu ti se mejeeji ni eewo fun awon alaigbagbo.”
الَّذِينَ اتَّخَذُوا دِينَهُمْ لَهْوًا وَلَعِبًا وَغَرَّتْهُمُ الْحَيَاةُ الدُّنْيَا ۚ فَالْيَوْمَ نَنْسَاهُمْ كَمَا نَسُوا لِقَاءَ يَوْمِهِمْ هَٰذَا وَمَا كَانُوا بِآيَاتِنَا يَجْحَدُونَ
Awon t’o so esin won di iranu ati ere sise, isemi aye si ko etan ba won, ni oni ni A oo gbagbe won gege bi won se gbagbe ipade ojo won ti oni yii ati (bi) won se n tako awon ayah Wa
وَلَقَدْ جِئْنَاهُمْ بِكِتَابٍ فَصَّلْنَاهُ عَلَىٰ عِلْمٍ هُدًى وَرَحْمَةً لِقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ
A kuku ti mu tira kan wa ba won, ti A salaye re pelu imo. (O je) imona ati ike fun ijo onigbagbo ododo
هَلْ يَنْظُرُونَ إِلَّا تَأْوِيلَهُ ۚ يَوْمَ يَأْتِي تَأْوِيلُهُ يَقُولُ الَّذِينَ نَسُوهُ مِنْ قَبْلُ قَدْ جَاءَتْ رُسُلُ رَبِّنَا بِالْحَقِّ فَهَلْ لَنَا مِنْ شُفَعَاءَ فَيَشْفَعُوا لَنَا أَوْ نُرَدُّ فَنَعْمَلَ غَيْرَ الَّذِي كُنَّا نَعْمَلُ ۚ قَدْ خَسِرُوا أَنْفُسَهُمْ وَضَلَّ عَنْهُمْ مَا كَانُوا يَفْتَرُونَ
Ki ni won n reti bi ko se imuse oro Re? Lojo ti imuse oro Re ba de, awon t’o gbagbe re siwaju yoo wi pe: “Dajudaju awon Ojise Oluwa wa ti mu ododo wa. Nitori naa, nje a le ri awon olusipe, ki won wa sipe fun wa tabi ki won da wa pada sile aye, ki a le se ise miiran yato si eyi ti a maa n se?” Dajudaju won ti se emi won lofo. Ohun ti won si n da ni adapa iro ti di ofo mo won lowo
إِنَّ رَبَّكُمُ اللَّهُ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٍ ثُمَّ اسْتَوَىٰ عَلَى الْعَرْشِ يُغْشِي اللَّيْلَ النَّهَارَ يَطْلُبُهُ حَثِيثًا وَالشَّمْسَ وَالْقَمَرَ وَالنُّجُومَ مُسَخَّرَاتٍ بِأَمْرِهِ ۗ أَلَا لَهُ الْخَلْقُ وَالْأَمْرُ ۗ تَبَارَكَ اللَّهُ رَبُّ الْعَالَمِينَ
Dajudaju Oluwa yin ni Allahu, Eni ti O seda awon sanmo ati ile fun ojo mefa. Leyin naa, O gunwa si ori Ite-ola. O n fi oru bo osan loju, ti oru n wa osan ni kiakia. Oorun, osupa ati awon irawo ni won ti ro pelu ase Re. Gbo! TiRe ni eda ati ase. Ibukun ni fun Allahu, Oluwa gbogbo eda

Choose other languages: