Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Araf Ayahs #22 Translated in Yoruba

قَالَ اخْرُجْ مِنْهَا مَذْءُومًا مَدْحُورًا ۖ لَمَنْ تَبِعَكَ مِنْهُمْ لَأَمْلَأَنَّ جَهَنَّمَ مِنْكُمْ أَجْمَعِينَ
(Allahu) so pe: "Jade kuro nibi (ki o si di) alabuku, eni-aledanu. Dajudaju enikeni t’o ba tele o ninu won, dajudaju Emi yoo fi gbogbo yin kun inu ina Jahanamo
وَيَا آدَمُ اسْكُنْ أَنْتَ وَزَوْجُكَ الْجَنَّةَ فَكُلَا مِنْ حَيْثُ شِئْتُمَا وَلَا تَقْرَبَا هَٰذِهِ الشَّجَرَةَ فَتَكُونَا مِنَ الظَّالِمِينَ
Adam, ki iwo ati iyawo re maa gbe ninu Ogba Idera. Nitori naa, e maa je nibikibi ti e ba fe. Ki e si ma se sunmo igi yii nitori ki e ma baa wa ninu awon alabosi
فَوَسْوَسَ لَهُمَا الشَّيْطَانُ لِيُبْدِيَ لَهُمَا مَا وُورِيَ عَنْهُمَا مِنْ سَوْآتِهِمَا وَقَالَ مَا نَهَاكُمَا رَبُّكُمَا عَنْ هَٰذِهِ الشَّجَرَةِ إِلَّا أَنْ تَكُونَا مَلَكَيْنِ أَوْ تَكُونَا مِنَ الْخَالِدِينَ
Esu si ko royiroyi ba awon mejeeji nitori ki o le fi ohun ti A fi pamo ninu ihoho ara won han won. O si wi pe: "Oluwa eyin mejeeji ko ko igi yii fun yin bi ko se pe ki eyin mejeeji ma baa di molaika tabi ki eyin mejeeji ma baa di olusegbere
وَقَاسَمَهُمَا إِنِّي لَكُمَا لَمِنَ النَّاصِحِينَ
O si bura fun awon mejeeji pe: "Dajudaju emi wa ninu awon onimoran fun eyin mejeeji
فَدَلَّاهُمَا بِغُرُورٍ ۚ فَلَمَّا ذَاقَا الشَّجَرَةَ بَدَتْ لَهُمَا سَوْآتُهُمَا وَطَفِقَا يَخْصِفَانِ عَلَيْهِمَا مِنْ وَرَقِ الْجَنَّةِ ۖ وَنَادَاهُمَا رَبُّهُمَا أَلَمْ أَنْهَكُمَا عَنْ تِلْكُمَا الشَّجَرَةِ وَأَقُلْ لَكُمَا إِنَّ الشَّيْطَانَ لَكُمَا عَدُوٌّ مُبِينٌ
O si tan awon mejeeji je. Nigba ti awon mejeeji to igi naa wo, ihoho awon mejeeji si han sira won. Won ba bere si fi awon ewe Ogba Idera bora won. Oluwa awon mejeeji si pe won pe: "Nje Emi ko ti ko igi naa fun eyin mejeeji? (Se) Emi ko si ti so fun eyin mejeeji pe ota ponnbele ni Esu je fun yin

Choose other languages: