Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Araf Ayahs #145 Translated in Yoruba

وَإِذْ أَنْجَيْنَاكُمْ مِنْ آلِ فِرْعَوْنَ يَسُومُونَكُمْ سُوءَ الْعَذَابِ ۖ يُقَتِّلُونَ أَبْنَاءَكُمْ وَيَسْتَحْيُونَ نِسَاءَكُمْ ۚ وَفِي ذَٰلِكُمْ بَلَاءٌ مِنْ رَبِّكُمْ عَظِيمٌ
(E ranti) nigba ti A la yin lowo awon eniyan Fir‘aon ti won n fi iya buruku je yin, won n pa awon omokunrin yin taara, won si n da awon omobinrin yin si. Adanwo nla wa ninu iyen lati odo Oluwa yin
وَوَاعَدْنَا مُوسَىٰ ثَلَاثِينَ لَيْلَةً وَأَتْمَمْنَاهَا بِعَشْرٍ فَتَمَّ مِيقَاتُ رَبِّهِ أَرْبَعِينَ لَيْلَةً ۚ وَقَالَ مُوسَىٰ لِأَخِيهِ هَارُونَ اخْلُفْنِي فِي قَوْمِي وَأَصْلِحْ وَلَا تَتَّبِعْ سَبِيلَ الْمُفْسِدِينَ
Ati pe A yan ogbon oru fun (Anabi) Musa. A tun fi mewaa kun un. Nitori naa, akoko (ti) Oluwa Re (yoo fi ba a soro si maa) pari ni oru ogoji. (Anabi) Musa so fun arakunrin re, Harun, pe: “Role de mi laaarin awon eniyan mi. Ki o maa se atunse. Ma si se tele ona awon obileje.”
وَلَمَّا جَاءَ مُوسَىٰ لِمِيقَاتِنَا وَكَلَّمَهُ رَبُّهُ قَالَ رَبِّ أَرِنِي أَنْظُرْ إِلَيْكَ ۚ قَالَ لَنْ تَرَانِي وَلَٰكِنِ انْظُرْ إِلَى الْجَبَلِ فَإِنِ اسْتَقَرَّ مَكَانَهُ فَسَوْفَ تَرَانِي ۚ فَلَمَّا تَجَلَّىٰ رَبُّهُ لِلْجَبَلِ جَعَلَهُ دَكًّا وَخَرَّ مُوسَىٰ صَعِقًا ۚ فَلَمَّا أَفَاقَ قَالَ سُبْحَانَكَ تُبْتُ إِلَيْكَ وَأَنَا أَوَّلُ الْمُؤْمِنِينَ
Nigba ti (Anabi) Musa de ni akoko ti A fun un, Oluwa re si ba a soro. (Anabi Musa) so pe: “Oluwa mi, fi ara Re han mi, ki emi le ri O.” (Allahu) so pe: “Iwo ko le ri Mi. Sugbon wo apata (yii), ti o ba duro sinsin si aye re, laipe o maa ri Mi.” Nigba ti Oluwa re si (rora) fi ara Re han apata, O so o di petele. (Anabi) Musa si subu lule, o daku. Nigba ti o taji, o so pe: “Mimo ni fun O, emi ronu piwada si odo Re. Emi si ni akoko awon onigbagbo ododo (ni asiko temi)
قَالَ يَا مُوسَىٰ إِنِّي اصْطَفَيْتُكَ عَلَى النَّاسِ بِرِسَالَاتِي وَبِكَلَامِي فَخُذْ مَا آتَيْتُكَ وَكُنْ مِنَ الشَّاكِرِينَ
(Allahu) so pe: "Musa, dajudaju Emi sa o lesa lori awon eniyan pelu awon ise Mi ati oro Mi. Nitori naa, gba ohun ti Mo fun o mu. Ki o si wa ninu awon oludupe
وَكَتَبْنَا لَهُ فِي الْأَلْوَاحِ مِنْ كُلِّ شَيْءٍ مَوْعِظَةً وَتَفْصِيلًا لِكُلِّ شَيْءٍ فَخُذْهَا بِقُوَّةٍ وَأْمُرْ قَوْمَكَ يَأْخُذُوا بِأَحْسَنِهَا ۚ سَأُرِيكُمْ دَارَ الْفَاسِقِينَ
A si ko gbogbo nnkan fun un sinu awon walaa. (O je) waasi ati alaye oro fun gbogbo nnkan. Nitori naa, samulo re daradara. Ki o si pa ijo re lase pe ki won samulo nnkan daadaa t’o n be ninu re. Emi yoo fi ile awon arufin han yin

Choose other languages: