Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Ankabut Ayahs #62 Translated in Yoruba

وَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَنُبَوِّئَنَّهُمْ مِنَ الْجَنَّةِ غُرَفًا تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا ۚ نِعْمَ أَجْرُ الْعَامِلِينَ
Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, dajudaju A maa fi won sinu awon ile peteesi giga kan ninu Ogba Idera, ti odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re. Esan awon oluse-rere si dara
الَّذِينَ صَبَرُوا وَعَلَىٰ رَبِّهِمْ يَتَوَكَّلُونَ
(Awon ni) awon t’o se suuru. Oluwa won si ni won n gbarale
وَكَأَيِّنْ مِنْ دَابَّةٍ لَا تَحْمِلُ رِزْقَهَا اللَّهُ يَرْزُقُهَا وَإِيَّاكُمْ ۚ وَهُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ
Meloo meloo ninu awon eranko ti ko le da bukata ije-imu re gbe, ti Allahu si n se ije-imu fun awon ati eyin. Oun si ni Olugbo, Onimo
وَلَئِنْ سَأَلْتَهُمْ مَنْ خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَسَخَّرَ الشَّمْسَ وَالْقَمَرَ لَيَقُولُنَّ اللَّهُ ۖ فَأَنَّىٰ يُؤْفَكُونَ
Ti o ba bi won leere pe: “Ta ni O da awon sanmo ati ile, ti O si ro oorun ati osupa?”, dajudaju won a wi pe: “Allahu ni.” Nitori naa, bawo ni won se n seri won kuro nibi ododo
اللَّهُ يَبْسُطُ الرِّزْقَ لِمَنْ يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ وَيَقْدِرُ لَهُ ۚ إِنَّ اللَّهَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ
Allahu l’O n te oro sile fun eni ti O ba fe ninu awon erusin Re. O si n diwon re fun elomiiran. Dajudaju Allahu ni Onimo nipa gbogbo nnkan

Choose other languages: