Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Ankabut Ayahs #50 Translated in Yoruba

وَلَا تُجَادِلُوا أَهْلَ الْكِتَابِ إِلَّا بِالَّتِي هِيَ أَحْسَنُ إِلَّا الَّذِينَ ظَلَمُوا مِنْهُمْ ۖ وَقُولُوا آمَنَّا بِالَّذِي أُنْزِلَ إِلَيْنَا وَأُنْزِلَ إِلَيْكُمْ وَإِلَٰهُنَا وَإِلَٰهُكُمْ وَاحِدٌ وَنَحْنُ لَهُ مُسْلِمُونَ
E ma se ba ahlul-kitab sariyan jiyan afi ni ona t’o dara julo (eyi ni lilo al-Ƙur’an ati hadith. E ma si se ja won logun) afi awon t’o ba sabosi ninu won. Ki e si so pe: “A gbagbo ninu ohun ti Won sokale fun awa ati ohun ti Won sokale fun eyin. Olohun wa ati Olohun yin, (Allahu) Okan soso ni. Awa si ni musulumi (olujuwo-juse-sile) fun Un.”
وَكَذَٰلِكَ أَنْزَلْنَا إِلَيْكَ الْكِتَابَ ۚ فَالَّذِينَ آتَيْنَاهُمُ الْكِتَابَ يُؤْمِنُونَ بِهِ ۖ وَمِنْ هَٰؤُلَاءِ مَنْ يُؤْمِنُ بِهِ ۚ وَمَا يَجْحَدُ بِآيَاتِنَا إِلَّا الْكَافِرُونَ
Bayen ni A se so Tira kale fun o. Nitori naa, awon ti A fun ni Tira, won gba a gbo. O si wa ninu awon wonyi (iyen, awon ara Mokkah), eni t’o gba a gbo. Ko si si eni t’o n tako awon ayah Wa afi awon alaigbagbo
وَمَا كُنْتَ تَتْلُو مِنْ قَبْلِهِ مِنْ كِتَابٍ وَلَا تَخُطُّهُ بِيَمِينِكَ ۖ إِذًا لَارْتَابَ الْمُبْطِلُونَ
Iwo ko ke tira kan ri siwaju al-Ƙur’an, iwo ko si fi owo otun re ko nnkan ri. Bi bee ko nigba naa, ki awon opuro seyemeji (si al-Ƙur’an)
بَلْ هُوَ آيَاتٌ بَيِّنَاتٌ فِي صُدُورِ الَّذِينَ أُوتُوا الْعِلْمَ ۚ وَمَا يَجْحَدُ بِآيَاتِنَا إِلَّا الظَّالِمُونَ
Rara (ko ri bi won se ro o. al-Ƙur’an), ohun ni awon ayah t’o yanju ninu igba-aya awon ti A fun ni imo-esin. Ko si si eni t’o n tako awon ayah Wa afi awon alabosi
وَقَالُوا لَوْلَا أُنْزِلَ عَلَيْهِ آيَاتٌ مِنْ رَبِّهِ ۖ قُلْ إِنَّمَا الْآيَاتُ عِنْدَ اللَّهِ وَإِنَّمَا أَنَا نَذِيرٌ مُبِينٌ
Won si wi pe: “Nitori ki ni Won ko se so awon ami (iyanu) kan kale fun un lati odo Oluwa re?” So pe: “Allahu nikan ni awon ami (iyanu) wa lodo Re. Ati pe olukilo ponnbele ni emi.”

Choose other languages: