Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Ankabut Ayahs #48 Translated in Yoruba

خَلَقَ اللَّهُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ بِالْحَقِّ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً لِلْمُؤْمِنِينَ
Allahu seda awon sanmo ati ile pelu ododo. Dajudaju ami kan wa ninu iyen fun awon onigbagbo ododo
اتْلُ مَا أُوحِيَ إِلَيْكَ مِنَ الْكِتَابِ وَأَقِمِ الصَّلَاةَ ۖ إِنَّ الصَّلَاةَ تَنْهَىٰ عَنِ الْفَحْشَاءِ وَالْمُنْكَرِ ۗ وَلَذِكْرُ اللَّهِ أَكْبَرُ ۗ وَاللَّهُ يَعْلَمُ مَا تَصْنَعُونَ
Ke ohun ti A fi ranse si o ninu Tira. Ki o si kirun. Dajudaju irun kiki n ko iwa ibaje ati aburu. Ati pe iranti Allahu tobi julo. Allahu si mo ohun ti e n se. bi irun kiki se ni esan bee naa lo tun je ohun t’o n mu olukirun jinna si iwa aburu aawe gbigba ati bee bee lo. Enikeni ti o ba pa irun kiki ati aawe gbigba ti nipase fifun gbolohun yii ni itumo odi o ti ko iparun ba emi ara re ni ibamu si surah al-Muddaththir; 74: 42-43. Ki Allahu (subhanahu wa ta’ala) la wa ninu eyi
وَلَا تُجَادِلُوا أَهْلَ الْكِتَابِ إِلَّا بِالَّتِي هِيَ أَحْسَنُ إِلَّا الَّذِينَ ظَلَمُوا مِنْهُمْ ۖ وَقُولُوا آمَنَّا بِالَّذِي أُنْزِلَ إِلَيْنَا وَأُنْزِلَ إِلَيْكُمْ وَإِلَٰهُنَا وَإِلَٰهُكُمْ وَاحِدٌ وَنَحْنُ لَهُ مُسْلِمُونَ
E ma se ba ahlul-kitab sariyan jiyan afi ni ona t’o dara julo (eyi ni lilo al-Ƙur’an ati hadith. E ma si se ja won logun) afi awon t’o ba sabosi ninu won. Ki e si so pe: “A gbagbo ninu ohun ti Won sokale fun awa ati ohun ti Won sokale fun eyin. Olohun wa ati Olohun yin, (Allahu) Okan soso ni. Awa si ni musulumi (olujuwo-juse-sile) fun Un.”
وَكَذَٰلِكَ أَنْزَلْنَا إِلَيْكَ الْكِتَابَ ۚ فَالَّذِينَ آتَيْنَاهُمُ الْكِتَابَ يُؤْمِنُونَ بِهِ ۖ وَمِنْ هَٰؤُلَاءِ مَنْ يُؤْمِنُ بِهِ ۚ وَمَا يَجْحَدُ بِآيَاتِنَا إِلَّا الْكَافِرُونَ
Bayen ni A se so Tira kale fun o. Nitori naa, awon ti A fun ni Tira, won gba a gbo. O si wa ninu awon wonyi (iyen, awon ara Mokkah), eni t’o gba a gbo. Ko si si eni t’o n tako awon ayah Wa afi awon alaigbagbo
وَمَا كُنْتَ تَتْلُو مِنْ قَبْلِهِ مِنْ كِتَابٍ وَلَا تَخُطُّهُ بِيَمِينِكَ ۖ إِذًا لَارْتَابَ الْمُبْطِلُونَ
Iwo ko ke tira kan ri siwaju al-Ƙur’an, iwo ko si fi owo otun re ko nnkan ri. Bi bee ko nigba naa, ki awon opuro seyemeji (si al-Ƙur’an)

Choose other languages: