Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anfal Ayahs #40 Translated in Yoruba

إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا يُنْفِقُونَ أَمْوَالَهُمْ لِيَصُدُّوا عَنْ سَبِيلِ اللَّهِ ۚ فَسَيُنْفِقُونَهَا ثُمَّ تَكُونُ عَلَيْهِمْ حَسْرَةً ثُمَّ يُغْلَبُونَ ۗ وَالَّذِينَ كَفَرُوا إِلَىٰ جَهَنَّمَ يُحْشَرُونَ
Dajudaju awon t’o sai gbagbo, won n na dukia won nitori ki won le seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu. Won si n na a lo (bee). Leyin naa, o maa di abamo fun won. Leyin naa, A si maa bori won. Ati pe awon t’o sai gbagbo, inu ina Jahanamo ni A maa ko won jo si
لِيَمِيزَ اللَّهُ الْخَبِيثَ مِنَ الطَّيِّبِ وَيَجْعَلَ الْخَبِيثَ بَعْضَهُ عَلَىٰ بَعْضٍ فَيَرْكُمَهُ جَمِيعًا فَيَجْعَلَهُ فِي جَهَنَّمَ ۚ أُولَٰئِكَ هُمُ الْخَاسِرُونَ
nitori ki Allahu le ya awon eni ibi soto kuro lara awon eni ire ati nitori ki O le ko awon eni ibi papo; apa kan won mo apa kan, ki O si le ro gbogbo won papo patapata (soju kan naa), O si maa fi won sinu ina Jahanamo. Awon wonyen, awon ni eni ofo
قُلْ لِلَّذِينَ كَفَرُوا إِنْ يَنْتَهُوا يُغْفَرْ لَهُمْ مَا قَدْ سَلَفَ وَإِنْ يَعُودُوا فَقَدْ مَضَتْ سُنَّتُ الْأَوَّلِينَ
So fun awon t’o sai gbagbo pe ti won ba jawo (ninu aigbagbo), A maa saforijin ohun t’o ti re koja fun won. Ti won ba tun pada (sibe, apejuwe) iparun awon eni akoko kuku ti re koja (ni ikilo fun won)
وَقَاتِلُوهُمْ حَتَّىٰ لَا تَكُونَ فِتْنَةٌ وَيَكُونَ الدِّينُ كُلُّهُ لِلَّهِ ۚ فَإِنِ انْتَهَوْا فَإِنَّ اللَّهَ بِمَا يَعْمَلُونَ بَصِيرٌ
E ja won logun titi ko fi nii si ifooro (iborisa) mo, gbogbo esin yo si le je ti Allahu. Nitori naa, ti won ba jawo (ninu aigbagbo), dajudaju Allahu ni Oluriran nipa ohun ti won n se nise
وَإِنْ تَوَلَّوْا فَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ مَوْلَاكُمْ ۚ نِعْمَ الْمَوْلَىٰ وَنِعْمَ النَّصِيرُ
Ti won ba si gbunri (kuro ninu igbagbo), e mo pe dajudaju Allahu ni Alafeyinti yin. O dara ni Alafeyinti. O si dara ni Alaranse

Choose other languages: