Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anfal Ayahs #35 Translated in Yoruba

وَإِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِمْ آيَاتُنَا قَالُوا قَدْ سَمِعْنَا لَوْ نَشَاءُ لَقُلْنَا مِثْلَ هَٰذَا ۙ إِنْ هَٰذَا إِلَّا أَسَاطِيرُ الْأَوَّلِينَ
Nigba ti A ba n ke awon ayah Wa fun won, won a wi pe: “A kuku ti gbo. Ti o ba je pe a ba fe ni. awa naa iba so iru eyi. Ki ni eyi bi ko se akosile alo awon eni akoko.”
وَإِذْ قَالُوا اللَّهُمَّ إِنْ كَانَ هَٰذَا هُوَ الْحَقَّ مِنْ عِنْدِكَ فَأَمْطِرْ عَلَيْنَا حِجَارَةً مِنَ السَّمَاءِ أَوِ ائْتِنَا بِعَذَابٍ أَلِيمٍ
(Ranti) nigba ti won wi pe: “Allahu, ti o ba je pe eyi ni ododo lati odo Re, ro ojo okuta le wa lori lati sanmo tabi ki O mu iya eleta-elero kan wa ba wa.”
وَمَا كَانَ اللَّهُ لِيُعَذِّبَهُمْ وَأَنْتَ فِيهِمْ ۚ وَمَا كَانَ اللَّهُ مُعَذِّبَهُمْ وَهُمْ يَسْتَغْفِرُونَ
Allahu ko nii je won niya nigba ti iwo si n be laaarin won. Allahu ko si nii je won niya nigba ti won si n toro aforijin
وَمَا لَهُمْ أَلَّا يُعَذِّبَهُمُ اللَّهُ وَهُمْ يَصُدُّونَ عَنِ الْمَسْجِدِ الْحَرَامِ وَمَا كَانُوا أَوْلِيَاءَهُ ۚ إِنْ أَوْلِيَاؤُهُ إِلَّا الْمُتَّقُونَ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَهُمْ لَا يَعْلَمُونَ
Ko si idi ti Allahu ko fi nii je won niya niwon igba ti won ba n se awon eniyan lori kuro ninu Mosalasi Haram. Ati pe awon osebo ko ni alamojuuto re. Ko si alamojuuto kan fun un bi ko se awon oluberu (Allahu), sugbon opolopo won ni ko mo
وَمَا كَانَ صَلَاتُهُمْ عِنْدَ الْبَيْتِ إِلَّا مُكَاءً وَتَصْدِيَةً ۚ فَذُوقُوا الْعَذَابَ بِمَا كُنْتُمْ تَكْفُرُونَ
Ijosin awon osebo ni Ile (Kaabah) ko si tayo sisu ife ati pipa atewo. Nitori naa, e to Iya wo nitori pe e je alaigbagbo

Choose other languages: