Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anaam Ayahs #148 Translated in Yoruba

وَمِنَ الْإِبِلِ اثْنَيْنِ وَمِنَ الْبَقَرِ اثْنَيْنِ ۗ قُلْ آلذَّكَرَيْنِ حَرَّمَ أَمِ الْأُنْثَيَيْنِ أَمَّا اشْتَمَلَتْ عَلَيْهِ أَرْحَامُ الْأُنْثَيَيْنِ ۖ أَمْ كُنْتُمْ شُهَدَاءَ إِذْ وَصَّاكُمُ اللَّهُ بِهَٰذَا ۚ فَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنِ افْتَرَىٰ عَلَى اللَّهِ كَذِبًا لِيُضِلَّ النَّاسَ بِغَيْرِ عِلْمٍ ۗ إِنَّ اللَّهَ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ
Meji ninu rakunmi (tako-tabo) ati meji ninu maalu (tako-tabo). So pe: "Se awon ako mejeeji ni Allahu se ni eewo ni tabi abo mejeeji, tabi ohun ti n be ninu apo-ibimo awon abo eran mejeeji. Tabi se eyin wa nibe nigba ti Allahu pa yin lase eyi ni?" Nitori naa, ta ni o se abosi t’o tun tayo eni t’o da adapa iro mo Allahu lati le si awon eniyan lona pelu ainimo. Dajudaju Allahu ko nii fi ona mo ijo alabosi
قُلْ لَا أَجِدُ فِي مَا أُوحِيَ إِلَيَّ مُحَرَّمًا عَلَىٰ طَاعِمٍ يَطْعَمُهُ إِلَّا أَنْ يَكُونَ مَيْتَةً أَوْ دَمًا مَسْفُوحًا أَوْ لَحْمَ خِنْزِيرٍ فَإِنَّهُ رِجْسٌ أَوْ فِسْقًا أُهِلَّ لِغَيْرِ اللَّهِ بِهِ ۚ فَمَنِ اضْطُرَّ غَيْرَ بَاغٍ وَلَا عَادٍ فَإِنَّ رَبَّكَ غَفُورٌ رَحِيمٌ
So pe: "Emi ko ri ninu ohun ti Won fi ranse si mi ti Won se jije re ni eewo fun eni ti o n je e afi ohun ti o ba je eran okunbete tabi eje sisan,1 tabi eran elede nitori pe dajudaju egbin ni, tabi eran iyapa (ase Allahu) ti won pa pelu oruko t’o yato si Allahu. Nitori naa, enikeni ti inira (ebi) ba mu je e, yato si eni t’o n wa eewo kiri ati olutayo-enu-ala, dajudaju Oluwa re ni Alaforijin, Asake-orun
وَعَلَى الَّذِينَ هَادُوا حَرَّمْنَا كُلَّ ذِي ظُفُرٍ ۖ وَمِنَ الْبَقَرِ وَالْغَنَمِ حَرَّمْنَا عَلَيْهِمْ شُحُومَهُمَا إِلَّا مَا حَمَلَتْ ظُهُورُهُمَا أَوِ الْحَوَايَا أَوْ مَا اخْتَلَطَ بِعَظْمٍ ۚ ذَٰلِكَ جَزَيْنَاهُمْ بِبَغْيِهِمْ ۖ وَإِنَّا لَصَادِقُونَ
A se e ni eewo fun awon t’o di yehudi gbogbo eran eleeekanna (tabi onipatako t’o supo mora won). Ninu eran maalu ati agutan, A tun se ora awon mejeeji ni eewo fun won afi eyi ti o ba le mo eyin won tabi ifun tabi eyi ti o ba ropo mo eegun. Iyen ni A fi san won ni esan nitori abosi owo won. Dajudaju Awa si ni Olododo
فَإِنْ كَذَّبُوكَ فَقُلْ رَبُّكُمْ ذُو رَحْمَةٍ وَاسِعَةٍ وَلَا يُرَدُّ بَأْسُهُ عَنِ الْقَوْمِ الْمُجْرِمِينَ
Ti won ba si pe o ni opuro, so nigba naa pe: "Oluwa yin ni Onikee to gbooro. Ko si si eni t’o le gbe iya Re kuro lori ijo elese
سَيَقُولُ الَّذِينَ أَشْرَكُوا لَوْ شَاءَ اللَّهُ مَا أَشْرَكْنَا وَلَا آبَاؤُنَا وَلَا حَرَّمْنَا مِنْ شَيْءٍ ۚ كَذَٰلِكَ كَذَّبَ الَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ حَتَّىٰ ذَاقُوا بَأْسَنَا ۗ قُلْ هَلْ عِنْدَكُمْ مِنْ عِلْمٍ فَتُخْرِجُوهُ لَنَا ۖ إِنْ تَتَّبِعُونَ إِلَّا الظَّنَّ وَإِنْ أَنْتُمْ إِلَّا تَخْرُصُونَ
Awon t’o n sebo yoo wi pe: "Ti ko ba je pe Allahu ba fe ni awa ati awon baba wa iba ti sebo, ati pe awa iba ti se nnkan kan leewo." Bayen ni awon t’o siwaju won se pe oro Allahu niro titi won fi to iya Wa wo. So pe: "Nje imo kan n be ni odo yin, ki e mu un jade fun wa?" Eyin ko tele kini kan bi ko se aroso. Ki si ni e n so bi ko se pe e n paro

Choose other languages: