Surah Al-Anaam Ayahs #123 Translated in Yoruba
وَمَا لَكُمْ أَلَّا تَأْكُلُوا مِمَّا ذُكِرَ اسْمُ اللَّهِ عَلَيْهِ وَقَدْ فَصَّلَ لَكُمْ مَا حَرَّمَ عَلَيْكُمْ إِلَّا مَا اضْطُرِرْتُمْ إِلَيْهِ ۗ وَإِنَّ كَثِيرًا لَيُضِلُّونَ بِأَهْوَائِهِمْ بِغَيْرِ عِلْمٍ ۗ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعْلَمُ بِالْمُعْتَدِينَ
Ki ni o maa ko fun yin lati je ninu ohun ti won fi oruko Allahu pa! O kuku ti salaye fun yin ohun ti O se ni eewo fun yin ayafi eyi ti inira (ebi) ba ti yin debe. Dajudaju opolopo ni won n fi ife-inu won pelu ainimo (won) si awon eniyan lona. Dajudaju Oluwa re, O nimo julo nipa awon olutayo enu-ala
وَذَرُوا ظَاهِرَ الْإِثْمِ وَبَاطِنَهُ ۚ إِنَّ الَّذِينَ يَكْسِبُونَ الْإِثْمَ سَيُجْزَوْنَ بِمَا كَانُوا يَقْتَرِفُونَ
E fi eyi t’o han ninu ese ati eyi t’o pamo ninu re sile. Dajudaju awon t’o n se ise ese, A oo san won ni esan ohun ti won n da lese
وَلَا تَأْكُلُوا مِمَّا لَمْ يُذْكَرِ اسْمُ اللَّهِ عَلَيْهِ وَإِنَّهُ لَفِسْقٌ ۗ وَإِنَّ الشَّيَاطِينَ لَيُوحُونَ إِلَىٰ أَوْلِيَائِهِمْ لِيُجَادِلُوكُمْ ۖ وَإِنْ أَطَعْتُمُوهُمْ إِنَّكُمْ لَمُشْرِكُونَ
Eyin ko si gbodo je ninu ohun ti won ko fi oruko Allahu pa. Dajudaju ibaje ni. Ati pe dajudaju awon esu, won yoo maa fi irande odu iro ranse si awon eni won, nitori ki won le tako yin. Ti e ba fi le tele won, dajudaju e ti di osebo
أَوَمَنْ كَانَ مَيْتًا فَأَحْيَيْنَاهُ وَجَعَلْنَا لَهُ نُورًا يَمْشِي بِهِ فِي النَّاسِ كَمَنْ مَثَلُهُ فِي الظُّلُمَاتِ لَيْسَ بِخَارِجٍ مِنْهَا ۚ كَذَٰلِكَ زُيِّنَ لِلْكَافِرِينَ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ
Nje eni ti (afiwe re) je oku (iyen, alaigbagbo), ti A so di alaaye (nipa pe o gba ’Islam), ti A si fun un ni imole (iyen, imo esin), ti o si n lo o laaarin awon eniyan, (nje) o da bi eni ti afiwe tire je (eni ti) n be ninu awon okunkun (aigbagbo), ti ko si jade kuro ninu re? Bayen ni won ti se ni oso fun awon alaigbagbo ohun ti won n se nise
وَكَذَٰلِكَ جَعَلْنَا فِي كُلِّ قَرْيَةٍ أَكَابِرَ مُجْرِمِيهَا لِيَمْكُرُوا فِيهَا ۖ وَمَا يَمْكُرُونَ إِلَّا بِأَنْفُسِهِمْ وَمَا يَشْعُرُونَ
Bayen ni A se so awon agba kan di odaran ilu ninu ilu kookan, nitori ki won le maa dete nibe. Won ko si dete si enikeni bi ko se si ara won, won ko si fura
Choose other languages:

Albanian

Amharic

Azerbaijani

Bengali

Bosnian

Bulgarian

Burmese

Chinese

Danish

Dutch

English

Farsi

Filipino

French

Fulah

German

Gujarati

Hausa

Hindi

Indonesian

Italian

Japanese

Jawa

Kazakh

Khmer

Korean

Kurdish

Kyrgyz

Malay

Malayalam

Norwegian

Pashto

Persian

Polish

Portuguese

Punjabi

Russian

Sindhi

Sinhalese

Somali

Spanish

Swahili

Swedish

Tajik

Tamil

Tatar

Telugu

Thai

Turkish

Urdu

Uyghur

Uzbek

Vietnamese

Yoruba
