Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anaam Ayahs #120 Translated in Yoruba

وَإِنْ تُطِعْ أَكْثَرَ مَنْ فِي الْأَرْضِ يُضِلُّوكَ عَنْ سَبِيلِ اللَّهِ ۚ إِنْ يَتَّبِعُونَ إِلَّا الظَّنَّ وَإِنْ هُمْ إِلَّا يَخْرُصُونَ
Ti o ba tele opolopo awon ti n be lori ile, won maa si o lona kuro loju ona (esin) Allahu. Won ko tele kini kan bi ko se aroso. Ki si ni won (n se) bi ko se pe won n paro
إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعْلَمُ مَنْ يَضِلُّ عَنْ سَبِيلِهِ ۖ وَهُوَ أَعْلَمُ بِالْمُهْتَدِينَ
Dajudaju Oluwa re, Oun l’O nimo julo nipa eni t’o sina loju ona (esin) Re. Ati pe, Oun si l’O nimo julo nipa awon olumona
فَكُلُوا مِمَّا ذُكِرَ اسْمُ اللَّهِ عَلَيْهِ إِنْ كُنْتُمْ بِآيَاتِهِ مُؤْمِنِينَ
Nitori naa, e je ninu ohun ti won ba fi oruko Allahu pa, ti e ba gbagbo ninu awon ayah Re
وَمَا لَكُمْ أَلَّا تَأْكُلُوا مِمَّا ذُكِرَ اسْمُ اللَّهِ عَلَيْهِ وَقَدْ فَصَّلَ لَكُمْ مَا حَرَّمَ عَلَيْكُمْ إِلَّا مَا اضْطُرِرْتُمْ إِلَيْهِ ۗ وَإِنَّ كَثِيرًا لَيُضِلُّونَ بِأَهْوَائِهِمْ بِغَيْرِ عِلْمٍ ۗ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعْلَمُ بِالْمُعْتَدِينَ
Ki ni o maa ko fun yin lati je ninu ohun ti won fi oruko Allahu pa! O kuku ti salaye fun yin ohun ti O se ni eewo fun yin ayafi eyi ti inira (ebi) ba ti yin debe. Dajudaju opolopo ni won n fi ife-inu won pelu ainimo (won) si awon eniyan lona. Dajudaju Oluwa re, O nimo julo nipa awon olutayo enu-ala
وَذَرُوا ظَاهِرَ الْإِثْمِ وَبَاطِنَهُ ۚ إِنَّ الَّذِينَ يَكْسِبُونَ الْإِثْمَ سَيُجْزَوْنَ بِمَا كَانُوا يَقْتَرِفُونَ
E fi eyi t’o han ninu ese ati eyi t’o pamo ninu re sile. Dajudaju awon t’o n se ise ese, A oo san won ni esan ohun ti won n da lese

Choose other languages: