Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anaam Ayahs #113 Translated in Yoruba

وَأَقْسَمُوا بِاللَّهِ جَهْدَ أَيْمَانِهِمْ لَئِنْ جَاءَتْهُمْ آيَةٌ لَيُؤْمِنُنَّ بِهَا ۚ قُلْ إِنَّمَا الْآيَاتُ عِنْدَ اللَّهِ ۖ وَمَا يُشْعِرُكُمْ أَنَّهَا إِذَا جَاءَتْ لَا يُؤْمِنُونَ
Won si fi Allahu bura ti ibura won si lagbara gan-an pe, dajudaju ti ami (iyanu) kan ba de ba awon, awon gbodo gba a gbo. So pe: "Odo Allahu nikan ni awon ami (iyanu) wa." Ki si ni o maa mu yin fura mo pe dajudaju nigba ti o ba de (ba won) won maa gba a gbo
وَنُقَلِّبُ أَفْئِدَتَهُمْ وَأَبْصَارَهُمْ كَمَا لَمْ يُؤْمِنُوا بِهِ أَوَّلَ مَرَّةٍ وَنَذَرُهُمْ فِي طُغْيَانِهِمْ يَعْمَهُونَ
A maa yi okan won ati oju won sodi ni; (won ko nii gba a gbo) gege bi won ko se gbagbo ninu (eyi t’o siwaju ninu awon ami iyanu) nigba akoko. A o si fi won sile sinu agbere won, ti won yoo maa pa ridarida
وَلَوْ أَنَّنَا نَزَّلْنَا إِلَيْهِمُ الْمَلَائِكَةَ وَكَلَّمَهُمُ الْمَوْتَىٰ وَحَشَرْنَا عَلَيْهِمْ كُلَّ شَيْءٍ قُبُلًا مَا كَانُوا لِيُؤْمِنُوا إِلَّا أَنْ يَشَاءَ اللَّهُ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَهُمْ يَجْهَلُونَ
Dajudaju ti A ba so awon molaika kale fun won, ti awon oku n ba won soro, ti A tun ko gbogbo nnkan jo siwaju won, won ko nii gbagbo afi ti Allahu ba fe. Sugbon opolopo won ni alaimokan
وَكَذَٰلِكَ جَعَلْنَا لِكُلِّ نَبِيٍّ عَدُوًّا شَيَاطِينَ الْإِنْسِ وَالْجِنِّ يُوحِي بَعْضُهُمْ إِلَىٰ بَعْضٍ زُخْرُفَ الْقَوْلِ غُرُورًا ۚ وَلَوْ شَاءَ رَبُّكَ مَا فَعَلُوهُ ۖ فَذَرْهُمْ وَمَا يَفْتَرُونَ
Bayen ni A ti se awon esu eniyan ati esu alujannu ni ota fun Anabi kookan; apa kan won n fi odu iro ranse si apa kan ni ti etan. Ti o ba je pe Oluwa re ba fe (lati to won sona ni) won iba ti se bee. Nitori naa, fi won sile tohun ti adapa iro ti won n da
وَلِتَصْغَىٰ إِلَيْهِ أَفْئِدَةُ الَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِالْآخِرَةِ وَلِيَرْضَوْهُ وَلِيَقْتَرِفُوا مَا هُمْ مُقْتَرِفُونَ
Ki awon okan ti won ko gba Ojo Ikeyin gbo maa teti beleje si (odu iro Esu), ki won maa yonu si i, ki won si maa da ohun ti won n da lese n so

Choose other languages: