Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Ahzab Ayahs #52 Translated in Yoruba

وَلَا تُطِعِ الْكَافِرِينَ وَالْمُنَافِقِينَ وَدَعْ أَذَاهُمْ وَتَوَكَّلْ عَلَى اللَّهِ ۚ وَكَفَىٰ بِاللَّهِ وَكِيلًا
Ma se tele awon alaigbagbo ati awon sobe-selu musulumi. Fi bi won se n ko inira ba o sile. Ki o si gbarale Allahu. Allahu si n to ni Alamojuuto
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِذَا نَكَحْتُمُ الْمُؤْمِنَاتِ ثُمَّ طَلَّقْتُمُوهُنَّ مِنْ قَبْلِ أَنْ تَمَسُّوهُنَّ فَمَا لَكُمْ عَلَيْهِنَّ مِنْ عِدَّةٍ تَعْتَدُّونَهَا ۖ فَمَتِّعُوهُنَّ وَسَرِّحُوهُنَّ سَرَاحًا جَمِيلًا
Eyin ti e gbagbo ni ododo lokunrin, nigba ti e ba fe awon onigbagbo ododo lobinrin, leyin naa ti e ko won sile siwaju ki e to ba won ni asepo loko-laya, ko si opo sise kan ti won yoo se fun yin. Nitori naa, e fun won ni ebun ikosile. Ki e si fi won sile ni ifisile t’o rewa
يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ إِنَّا أَحْلَلْنَا لَكَ أَزْوَاجَكَ اللَّاتِي آتَيْتَ أُجُورَهُنَّ وَمَا مَلَكَتْ يَمِينُكَ مِمَّا أَفَاءَ اللَّهُ عَلَيْكَ وَبَنَاتِ عَمِّكَ وَبَنَاتِ عَمَّاتِكَ وَبَنَاتِ خَالِكَ وَبَنَاتِ خَالَاتِكَ اللَّاتِي هَاجَرْنَ مَعَكَ وَامْرَأَةً مُؤْمِنَةً إِنْ وَهَبَتْ نَفْسَهَا لِلنَّبِيِّ إِنْ أَرَادَ النَّبِيُّ أَنْ يَسْتَنْكِحَهَا خَالِصَةً لَكَ مِنْ دُونِ الْمُؤْمِنِينَ ۗ قَدْ عَلِمْنَا مَا فَرَضْنَا عَلَيْهِمْ فِي أَزْوَاجِهِمْ وَمَا مَلَكَتْ أَيْمَانُهُمْ لِكَيْلَا يَكُونَ عَلَيْكَ حَرَجٌ ۗ وَكَانَ اللَّهُ غَفُورًا رَحِيمًا
Iwo Anabi, dajudaju Awa se e ni eto fun o awon iyawo re, ti o fun ni owo-ori won, ati awon eru ninu awon ti Allahu fi se ikogun fun o ati awon omobinrin arakunrin baba re ati awon omobinrin arabinrin baba re, ati awon omobinrin arakunrin iya re, ati awon omobinrin arabinrin iya re, awon t’o fi ilu Mokkah sile wa si ilu Modinah pelu re, ati onigbagbo ododo lobinrin, ti o ba fi ara re tore fun Anabi, ti Anabi naa si fe fi se iyawo. Iwo nikan ni (eyi) wa fun, ko si fun awon onigbagbo ododo lokunrin. A ti mo ohun ti A se ni oran-anyan fun won nipa awon iyawo won ati awon eru won. (Eyi ri bee) nitori ki o ma baa si laifi fun o. Allahu si n je Alaforijin, Asake-orun
تُرْجِي مَنْ تَشَاءُ مِنْهُنَّ وَتُؤْوِي إِلَيْكَ مَنْ تَشَاءُ ۖ وَمَنِ ابْتَغَيْتَ مِمَّنْ عَزَلْتَ فَلَا جُنَاحَ عَلَيْكَ ۚ ذَٰلِكَ أَدْنَىٰ أَنْ تَقَرَّ أَعْيُنُهُنَّ وَلَا يَحْزَنَّ وَيَرْضَيْنَ بِمَا آتَيْتَهُنَّ كُلُّهُنَّ ۚ وَاللَّهُ يَعْلَمُ مَا فِي قُلُوبِكُمْ ۚ وَكَانَ اللَّهُ عَلِيمًا حَلِيمًا
Lora lati sunmo eni ti o ba fe ninu won. Fa eni ti o ba fe mora. Ati pe eni keni ti o ba tun wa (lati sunmo) ninu awon ti o o pin oorun fun, ko si ese fun o (lati se bee). Iyen sunmo julo lati mu oju won tutu idunnu. Won ko si nii banuje. Gbogbo won yo si yonu si ohunkohun ti o ba fun won. Allahu mo ohun ti n be ninu okan yin. Allahu si n je Onimo, Alafarada
لَا يَحِلُّ لَكَ النِّسَاءُ مِنْ بَعْدُ وَلَا أَنْ تَبَدَّلَ بِهِنَّ مِنْ أَزْوَاجٍ وَلَوْ أَعْجَبَكَ حُسْنُهُنَّ إِلَّا مَا مَلَكَتْ يَمِينُكَ ۗ وَكَانَ اللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ رَقِيبًا
Ko letoo fun o (lati fe) awon obinrin (miiran) leyin (isori awon ti A se ni eto fun o, ko si letoo fun o) lati fi awon obinrin (miiran) paaro won, koda ki daadaa won jo o loju, afi awon eru re (nikan l’o le ko sile ninu awon iyawo re). Allahu si n je Oluso lori gbogbo nnkan

Choose other languages: