Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Ahzab Ayahs #49 Translated in Yoruba

يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ إِنَّا أَرْسَلْنَاكَ شَاهِدًا وَمُبَشِّرًا وَنَذِيرًا
Iwo Anabi, dajudaju Awa ran o nise (pe ki o je) olujerii, oniroo-idunnu, olukilo
وَدَاعِيًا إِلَى اللَّهِ بِإِذْنِهِ وَسِرَاجًا مُنِيرًا
olupepe si odo Allahu pelu iyonda Re ati atupa imole
وَبَشِّرِ الْمُؤْمِنِينَ بِأَنَّ لَهُمْ مِنَ اللَّهِ فَضْلًا كَبِيرًا
Fun awon onigbagbo ododo ni iro idunnu pe dajudaju oore ajulo nla wa fun won lodo Allahu
وَلَا تُطِعِ الْكَافِرِينَ وَالْمُنَافِقِينَ وَدَعْ أَذَاهُمْ وَتَوَكَّلْ عَلَى اللَّهِ ۚ وَكَفَىٰ بِاللَّهِ وَكِيلًا
Ma se tele awon alaigbagbo ati awon sobe-selu musulumi. Fi bi won se n ko inira ba o sile. Ki o si gbarale Allahu. Allahu si n to ni Alamojuuto
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِذَا نَكَحْتُمُ الْمُؤْمِنَاتِ ثُمَّ طَلَّقْتُمُوهُنَّ مِنْ قَبْلِ أَنْ تَمَسُّوهُنَّ فَمَا لَكُمْ عَلَيْهِنَّ مِنْ عِدَّةٍ تَعْتَدُّونَهَا ۖ فَمَتِّعُوهُنَّ وَسَرِّحُوهُنَّ سَرَاحًا جَمِيلًا
Eyin ti e gbagbo ni ododo lokunrin, nigba ti e ba fe awon onigbagbo ododo lobinrin, leyin naa ti e ko won sile siwaju ki e to ba won ni asepo loko-laya, ko si opo sise kan ti won yoo se fun yin. Nitori naa, e fun won ni ebun ikosile. Ki e si fi won sile ni ifisile t’o rewa

Choose other languages: