Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Ahzab Ayahs #34 Translated in Yoruba

يَا نِسَاءَ النَّبِيِّ مَنْ يَأْتِ مِنْكُنَّ بِفَاحِشَةٍ مُبَيِّنَةٍ يُضَاعَفْ لَهَا الْعَذَابُ ضِعْفَيْنِ ۚ وَكَانَ ذَٰلِكَ عَلَى اللَّهِ يَسِيرًا
Eyin iyawo Anabi, enikeni ninu yin ti o ba se ibaje t’o foju han, A maa di adipele iya ilopo meji fun un. Iyen si n je irorun fun Allahu
وَمَنْ يَقْنُتْ مِنْكُنَّ لِلَّهِ وَرَسُولِهِ وَتَعْمَلْ صَالِحًا نُؤْتِهَا أَجْرَهَا مَرَّتَيْنِ وَأَعْتَدْنَا لَهَا رِزْقًا كَرِيمًا
Enikeni ti o ba n tele ti Allahu ati ti Ojise Re ninu yin, ti o si n se ise rere, A maa fun un ni esan ilopo meji. A si ti pese ije-imu alapon-onle sile de e.”
يَا نِسَاءَ النَّبِيِّ لَسْتُنَّ كَأَحَدٍ مِنَ النِّسَاءِ ۚ إِنِ اتَّقَيْتُنَّ فَلَا تَخْضَعْنَ بِالْقَوْلِ فَيَطْمَعَ الَّذِي فِي قَلْبِهِ مَرَضٌ وَقُلْنَ قَوْلًا مَعْرُوفًا
Eyin iyawo Anabi, e o da bi eni kan kan ninu awon obinrin, ti e ba ti beru (Allahu). E ma se dinhun (si awon okunrin leti) nitori ki eni ti arun wa ninu okan re ma baa jerankan. Ki e si maa so oro t’o dara
وَقَرْنَ فِي بُيُوتِكُنَّ وَلَا تَبَرَّجْنَ تَبَرُّجَ الْجَاهِلِيَّةِ الْأُولَىٰ ۖ وَأَقِمْنَ الصَّلَاةَ وَآتِينَ الزَّكَاةَ وَأَطِعْنَ اللَّهَ وَرَسُولَهُ ۚ إِنَّمَا يُرِيدُ اللَّهُ لِيُذْهِبَ عَنْكُمُ الرِّجْسَ أَهْلَ الْبَيْتِ وَيُطَهِّرَكُمْ تَطْهِيرًا
E fidi mole yin. E ma se fi ara ati oso han nita gege bi ti ifara-foso-han igba aimokan akoko (iyen, siwaju ki e t’o di musulumi). E kirun. E yo Zakah. Ki e si tele (ase) Allahu ati (ase) Ojise Re. Allahu kan n gbero lati mu egbin kuro lara yin, eyin ara ile (Anabi). Ati pe O (kan n gbero lati) fo yin mo tonitoni ni
وَاذْكُرْنَ مَا يُتْلَىٰ فِي بُيُوتِكُنَّ مِنْ آيَاتِ اللَّهِ وَالْحِكْمَةِ ۚ إِنَّ اللَّهَ كَانَ لَطِيفًا خَبِيرًا
E ranti ohun ti won n ke ninu ile yin ninu awon ayah Allahu ati ijinle oye (iyen, sunnah Anabi). Dajudaju Allahu n je Alaaanu, Onimo-ikoko. ti Larubawa ba n d’oju oro ko okunrin tabi nnkan ako tabi o n soro nipa okunrin tabi nnkan ako ede Larubawa ti ni ihun ako fun ako. Bakan naa

Choose other languages: