Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Ahzab Ayahs #36 Translated in Yoruba

يَا نِسَاءَ النَّبِيِّ لَسْتُنَّ كَأَحَدٍ مِنَ النِّسَاءِ ۚ إِنِ اتَّقَيْتُنَّ فَلَا تَخْضَعْنَ بِالْقَوْلِ فَيَطْمَعَ الَّذِي فِي قَلْبِهِ مَرَضٌ وَقُلْنَ قَوْلًا مَعْرُوفًا
Eyin iyawo Anabi, e o da bi eni kan kan ninu awon obinrin, ti e ba ti beru (Allahu). E ma se dinhun (si awon okunrin leti) nitori ki eni ti arun wa ninu okan re ma baa jerankan. Ki e si maa so oro t’o dara
وَقَرْنَ فِي بُيُوتِكُنَّ وَلَا تَبَرَّجْنَ تَبَرُّجَ الْجَاهِلِيَّةِ الْأُولَىٰ ۖ وَأَقِمْنَ الصَّلَاةَ وَآتِينَ الزَّكَاةَ وَأَطِعْنَ اللَّهَ وَرَسُولَهُ ۚ إِنَّمَا يُرِيدُ اللَّهُ لِيُذْهِبَ عَنْكُمُ الرِّجْسَ أَهْلَ الْبَيْتِ وَيُطَهِّرَكُمْ تَطْهِيرًا
E fidi mole yin. E ma se fi ara ati oso han nita gege bi ti ifara-foso-han igba aimokan akoko (iyen, siwaju ki e t’o di musulumi). E kirun. E yo Zakah. Ki e si tele (ase) Allahu ati (ase) Ojise Re. Allahu kan n gbero lati mu egbin kuro lara yin, eyin ara ile (Anabi). Ati pe O (kan n gbero lati) fo yin mo tonitoni ni
وَاذْكُرْنَ مَا يُتْلَىٰ فِي بُيُوتِكُنَّ مِنْ آيَاتِ اللَّهِ وَالْحِكْمَةِ ۚ إِنَّ اللَّهَ كَانَ لَطِيفًا خَبِيرًا
E ranti ohun ti won n ke ninu ile yin ninu awon ayah Allahu ati ijinle oye (iyen, sunnah Anabi). Dajudaju Allahu n je Alaaanu, Onimo-ikoko. ti Larubawa ba n d’oju oro ko okunrin tabi nnkan ako tabi o n soro nipa okunrin tabi nnkan ako ede Larubawa ti ni ihun ako fun ako. Bakan naa
إِنَّ الْمُسْلِمِينَ وَالْمُسْلِمَاتِ وَالْمُؤْمِنِينَ وَالْمُؤْمِنَاتِ وَالْقَانِتِينَ وَالْقَانِتَاتِ وَالصَّادِقِينَ وَالصَّادِقَاتِ وَالصَّابِرِينَ وَالصَّابِرَاتِ وَالْخَاشِعِينَ وَالْخَاشِعَاتِ وَالْمُتَصَدِّقِينَ وَالْمُتَصَدِّقَاتِ وَالصَّائِمِينَ وَالصَّائِمَاتِ وَالْحَافِظِينَ فُرُوجَهُمْ وَالْحَافِظَاتِ وَالذَّاكِرِينَ اللَّهَ كَثِيرًا وَالذَّاكِرَاتِ أَعَدَّ اللَّهُ لَهُمْ مَغْفِرَةً وَأَجْرًا عَظِيمًا
Dajudaju awon musulumi lokunrin ati musulumi lobinrin, awon onigbagbo ododo lokunrin ati awon onigbagbo ododo lobinrin, awon olutele-ase Allahu lokunrin ati awon olutele-ase Allahu lobinrin, awon olododo lokunrin ati awon olododo lobinrin, awon onisuuru lokunrin ati awon onisuuru lobinrin, awon olupaya Allahu lokunrin ati awon olupaya Allahu lobinrin, awon olutore lokunrin ati awon olutore lobinrin, awon alaawe lokunrin ati awon alaawe lobinrin, awon t’o n so abe won lokunrin ati awon t’o n so abe won lobinrin, awon oluranti Allahu ni opolopo lokunrin ati awon oluranti Allahu (ni opolopo) lobinrin; Allahu ti pese aforijin ati esan nla sile de won
وَمَا كَانَ لِمُؤْمِنٍ وَلَا مُؤْمِنَةٍ إِذَا قَضَى اللَّهُ وَرَسُولُهُ أَمْرًا أَنْ يَكُونَ لَهُمُ الْخِيَرَةُ مِنْ أَمْرِهِمْ ۗ وَمَنْ يَعْصِ اللَّهَ وَرَسُولَهُ فَقَدْ ضَلَّ ضَلَالًا مُبِينًا
Ko to fun onigbagbo ododo lokunrin ati onigbagbo ododo lobinrin, nigba ti Allahu ati Ojise Re ba ti pari oro kan, lati ni esa (oro miiran) fun oro ara won. Ati pe enikeni ti o ba yapa (ase) Allahu ati (ase) Ojise Re, dajudaju o ti sina ni isina ponnbele

Choose other languages: