Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Ahzab Ayahs #17 Translated in Yoruba

وَإِذْ قَالَتْ طَائِفَةٌ مِنْهُمْ يَا أَهْلَ يَثْرِبَ لَا مُقَامَ لَكُمْ فَارْجِعُوا ۚ وَيَسْتَأْذِنُ فَرِيقٌ مِنْهُمُ النَّبِيَّ يَقُولُونَ إِنَّ بُيُوتَنَا عَوْرَةٌ وَمَا هِيَ بِعَوْرَةٍ ۖ إِنْ يُرِيدُونَ إِلَّا فِرَارًا
(E ranti) nigba ti igun kan ninu won wi pe: “Eyin ara Yethrib, ko si aye (isegun) fun yin, nitori naa, e seri pada (lodo Ojise).” Apa kan ninu won si n toro iyonda lowo Anabi, won n wi pe: “Dajudaju ile wa da paroparo ni.” (Ile won) ko si da paroparo. Won ko si gbero ohun kan tayo sisagun
وَلَوْ دُخِلَتْ عَلَيْهِمْ مِنْ أَقْطَارِهَا ثُمَّ سُئِلُوا الْفِتْنَةَ لَآتَوْهَا وَمَا تَلَبَّثُوا بِهَا إِلَّا يَسِيرًا
Ati pe ti o ba je pe (omo ogun onijo) wole to won wa lati awon iloro ilu (Modinah), leyin naa, ki won pe (awon sobe-selu musulumi) sinu ebo sise, won iba sebo. Won ko si nii gbe ninu ilu mo tayo igba die (ti won yoo fi pare)
وَلَقَدْ كَانُوا عَاهَدُوا اللَّهَ مِنْ قَبْلُ لَا يُوَلُّونَ الْأَدْبَارَ ۚ وَكَانَ عَهْدُ اللَّهِ مَسْئُولًا
Dajudaju won ti ba Allahu se adehun siwaju pe awon ko nii peyinda (lati sagun). Adehun Allahu si je ohun ti won maa beere (lowo won)
قُلْ لَنْ يَنْفَعَكُمُ الْفِرَارُ إِنْ فَرَرْتُمْ مِنَ الْمَوْتِ أَوِ الْقَتْلِ وَإِذًا لَا تُمَتَّعُونَ إِلَّا قَلِيلًا
So pe: “Sisagun yin ko le se yin ni anfaani, ti e ba sa fun iku tabi pipa (si oju ogun esin. Ti e ba si sagun) nigba naa, A o nii fun yin ni igbadun aye bi ko se fun igba die
قُلْ مَنْ ذَا الَّذِي يَعْصِمُكُمْ مِنَ اللَّهِ إِنْ أَرَادَ بِكُمْ سُوءًا أَوْ أَرَادَ بِكُمْ رَحْمَةً ۚ وَلَا يَجِدُونَ لَهُمْ مِنْ دُونِ اللَّهِ وَلِيًّا وَلَا نَصِيرًا
So pe: “Ta ni eni ti o le da aabo bo yin lodo Allahu ti O ba fe fi aburu kan yin tabi ti O ba fe ke yin?” Won ko si le ri alaabo tabi alaranse kan leyin Allahu

Choose other languages: