Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Ahqaf Ayahs #35 Translated in Yoruba

وَمَنْ لَا يُجِبْ دَاعِيَ اللَّهِ فَلَيْسَ بِمُعْجِزٍ فِي الْأَرْضِ وَلَيْسَ لَهُ مِنْ دُونِهِ أَوْلِيَاءُ ۚ أُولَٰئِكَ فِي ضَلَالٍ مُبِينٍ
Enikeni ti ko ba si jepe olupepe Allahu, ko le mori bo mo (Allahu) lowo lori ile. Ko si si alaabo kan fun un leyin Allahu. Awon wonyen si wa ninu isina ponnbele
أَوَلَمْ يَرَوْا أَنَّ اللَّهَ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَلَمْ يَعْيَ بِخَلْقِهِنَّ بِقَادِرٍ عَلَىٰ أَنْ يُحْيِيَ الْمَوْتَىٰ ۚ بَلَىٰ إِنَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Se won ko ri i pe dajudaju Allahu, Eni ti O da awon sanmo ati ile, ti ko si kaaare nipa iseda won, (se ko) ni agbara lati so awon oku di alaaye ni? Rara, (O lagbara lati se bee). Dajudaju O n je Alagbara lori gbogbo nnkan
وَيَوْمَ يُعْرَضُ الَّذِينَ كَفَرُوا عَلَى النَّارِ أَلَيْسَ هَٰذَا بِالْحَقِّ ۖ قَالُوا بَلَىٰ وَرَبِّنَا ۚ قَالَ فَذُوقُوا الْعَذَابَ بِمَا كُنْتُمْ تَكْفُرُونَ
(Ranti) ojo ti won maa dari awon t’o sai gbagbo lo sori Ina, (won si maa so fun won pe:) "Se eyi ki i se ododo bi?" Won yoo wi pe: "Rara, (ododo ni) Oluwa wa." (Allahu maa) so pe: "Nitori naa, e to iya wo nitori pe eyin je alaigbagbo
فَاصْبِرْ كَمَا صَبَرَ أُولُو الْعَزْمِ مِنَ الرُّسُلِ وَلَا تَسْتَعْجِلْ لَهُمْ ۚ كَأَنَّهُمْ يَوْمَ يَرَوْنَ مَا يُوعَدُونَ لَمْ يَلْبَثُوا إِلَّا سَاعَةً مِنْ نَهَارٍ ۚ بَلَاغٌ ۚ فَهَلْ يُهْلَكُ إِلَّا الْقَوْمُ الْفَاسِقُونَ
Nitori naa, se suuru gege bi awon onipinnu okan ninu awon Ojise ti se suuru. Ma se ba won wa iya pelu ikanju. Ni ojo ti won ba ri ohun ti A n se ni adehun fun won, won yoo da bi eni pe won ko gbe ile aye (yii) tayo akoko kan ninu osan. Al-Ƙur’an yii si ni ijise dopin. Ta ni o si maa parun bi ko se ijo obileje

Choose other languages: