Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Ahqaf Ayahs #6 Translated in Yoruba

تَنْزِيلُ الْكِتَابِ مِنَ اللَّهِ الْعَزِيزِ الْحَكِيمِ
Tira naa sokale lati odo Allahu, Alagbara, Ologbon
مَا خَلَقْنَا السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا إِلَّا بِالْحَقِّ وَأَجَلٍ مُسَمًّى ۚ وَالَّذِينَ كَفَرُوا عَمَّا أُنْذِرُوا مُعْرِضُونَ
A o seda awon sanmo ati ile, ati ohunkohun t’o wa laaarin mejeeji bi ko se pelu ododo ati fun gbedeke akoko kan. Awon t’o sai gbagbo yo si maa gbunri kuro nibi ohun ti A fi sekilo fun won
قُلْ أَرَأَيْتُمْ مَا تَدْعُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ أَرُونِي مَاذَا خَلَقُوا مِنَ الْأَرْضِ أَمْ لَهُمْ شِرْكٌ فِي السَّمَاوَاتِ ۖ ائْتُونِي بِكِتَابٍ مِنْ قَبْلِ هَٰذَا أَوْ أَثَارَةٍ مِنْ عِلْمٍ إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ
So pe: "E so fun mi nipa nnkan ti e n pe leyin Allahu; e fi won han mi na, ki ni won seda ninu (ohun t’o wa lori) ile. Tabi won ni ipin kan (pelu Allahu) ninu (iseda) awon sanmo? E mu Tira kan wa fun mi t’o siwaju (al-Ƙur’an) yii tabi oripa kan ninu imo ti e ba je olododo
وَمَنْ أَضَلُّ مِمَّنْ يَدْعُو مِنْ دُونِ اللَّهِ مَنْ لَا يَسْتَجِيبُ لَهُ إِلَىٰ يَوْمِ الْقِيَامَةِ وَهُمْ عَنْ دُعَائِهِمْ غَافِلُونَ
Ta l’o si sina ju eni ti o n pe leyin Allahu, eni ti ko le je ipe re titi di Ojo Ajinde! Ati pe won ko ni oye si pipe ti won n pe won
وَإِذَا حُشِرَ النَّاسُ كَانُوا لَهُمْ أَعْدَاءً وَكَانُوا بِعِبَادَتِهِمْ كَافِرِينَ
Nigba ti A ba si ko awon eniyan jo (fun Ajinde), awon orisa yoo di ota fun awon aborisa. Won si maa tako ijosin ti won se fun won

Choose other languages: