Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #85 Translated in Yoruba

وَإِذْ أَخَذَ اللَّهُ مِيثَاقَ النَّبِيِّينَ لَمَا آتَيْتُكُمْ مِنْ كِتَابٍ وَحِكْمَةٍ ثُمَّ جَاءَكُمْ رَسُولٌ مُصَدِّقٌ لِمَا مَعَكُمْ لَتُؤْمِنُنَّ بِهِ وَلَتَنْصُرُنَّهُ ۚ قَالَ أَأَقْرَرْتُمْ وَأَخَذْتُمْ عَلَىٰ ذَٰلِكُمْ إِصْرِي ۖ قَالُوا أَقْرَرْنَا ۚ قَالَ فَاشْهَدُوا وَأَنَا مَعَكُمْ مِنَ الشَّاهِدِينَ
(E ranti) nigba ti Allahu gba adehun lowo awon Anabi pe: “(E lo) eyi ti Mo ba fun yin ninu Tira ati ijinle oye (iyen, sunnah eni kookan won). Leyin naa, Ojise kan (iyen, Anabi Muhammad s.a.w.) yoo de ba yin; o maa fi eyi t’o je ododo rinle nipa eyi t’o wa pelu yin. Nitori naa, e gbodo gba a gbo, e si gbodo ran an lowo.” (Allahu) so pe: “Nje e gba? Se e si maa lo adehun Mi yii?” Won so pe: “A gba.” (Allahu) so pe: "Nitori naa, e jerii si (adehun naa). Emi n be pelu yin ninu awon Olujerii
فَمَنْ تَوَلَّىٰ بَعْدَ ذَٰلِكَ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْفَاسِقُونَ
Nitori naa, eni ti o ba keyin si (Anabi Muhammad s.a.w.) leyin (adehun) yen, awon wonyen ni obileje
أَفَغَيْرَ دِينِ اللَّهِ يَبْغُونَ وَلَهُ أَسْلَمَ مَنْ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ طَوْعًا وَكَرْهًا وَإِلَيْهِ يُرْجَعُونَ
Se esin miiran yato si esin Allahu ni won n wa ni? Nigba ti o je pe tiRe ni gbogbo eni ti n be ninu awon sanmo ati ile juwo juse sile fun, won fe won ko. Odo Re si ni Won maa da won pada si
قُلْ آمَنَّا بِاللَّهِ وَمَا أُنْزِلَ عَلَيْنَا وَمَا أُنْزِلَ عَلَىٰ إِبْرَاهِيمَ وَإِسْمَاعِيلَ وَإِسْحَاقَ وَيَعْقُوبَ وَالْأَسْبَاطِ وَمَا أُوتِيَ مُوسَىٰ وَعِيسَىٰ وَالنَّبِيُّونَ مِنْ رَبِّهِمْ لَا نُفَرِّقُ بَيْنَ أَحَدٍ مِنْهُمْ وَنَحْنُ لَهُ مُسْلِمُونَ
So pe: “A gbagbo ninu Allahu ati ohun ti Won sokale fun wa pelu ohun ti Won sokale fun (Anabi) ’Ibrohim, ’Ismo‘il, ’Ishaƙ, Ya‘ƙub, ati awon aromodomo (re. A gbagbo ninu) ohun ti Won fun (Anabi) Musa ati ‘Isa ati awon Anabi lati odo Oluwa won; A ko ya eni kan kan soto ninu won. Awa si ni musulumi (olujuwo-juse-sile) fun Un.”
وَمَنْ يَبْتَغِ غَيْرَ الْإِسْلَامِ دِينًا فَلَنْ يُقْبَلَ مِنْهُ وَهُوَ فِي الْآخِرَةِ مِنَ الْخَاسِرِينَ
Enikeni ti o ba wa esin kan se yato si ’Islam, A o nii gba a lowo re. Ni Ojo Ikeyin, o si maa wa ninu awon eni ofo

Choose other languages: