Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #29 Translated in Yoruba

فَكَيْفَ إِذَا جَمَعْنَاهُمْ لِيَوْمٍ لَا رَيْبَ فِيهِ وَوُفِّيَتْ كُلُّ نَفْسٍ مَا كَسَبَتْ وَهُمْ لَا يُظْلَمُونَ
Nitori naa, bawo ni (o se maa ri fun won) nigba ti A ba ko won jo ni ojo kan, ti ko si iyemeji ninu re? Ati pe A maa san emi kookan ni esan ohun ti o se nise ni ekun-rere. Won ko si nii sabosi si won
قُلِ اللَّهُمَّ مَالِكَ الْمُلْكِ تُؤْتِي الْمُلْكَ مَنْ تَشَاءُ وَتَنْزِعُ الْمُلْكَ مِمَّنْ تَشَاءُ وَتُعِزُّ مَنْ تَشَاءُ وَتُذِلُّ مَنْ تَشَاءُ ۖ بِيَدِكَ الْخَيْرُ ۖ إِنَّكَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
So pe: “Allahu, Olukapa ijoba, O n fi ijoba fun eni ti O ba fe. O n gba ijoba lowo eni ti O ba fe. O n buyi kun eni ti O ba fe. O si n tabuku eni ti O ba fe. Owo Re ni oore wa. Dajudaju Iwo ni Alagbara lori gbogbo nnkan
تُولِجُ اللَّيْلَ فِي النَّهَارِ وَتُولِجُ النَّهَارَ فِي اللَّيْلِ ۖ وَتُخْرِجُ الْحَيَّ مِنَ الْمَيِّتِ وَتُخْرِجُ الْمَيِّتَ مِنَ الْحَيِّ ۖ وَتَرْزُقُ مَنْ تَشَاءُ بِغَيْرِ حِسَابٍ
O n mu oru wonu osan. O n mu osan wonu oru. O n mu alaaye jade lara oku. O n mu oku jade lara alaaye. O si n se arisiki fun eni ti O ba fe ni opolopo.”
لَا يَتَّخِذِ الْمُؤْمِنُونَ الْكَافِرِينَ أَوْلِيَاءَ مِنْ دُونِ الْمُؤْمِنِينَ ۖ وَمَنْ يَفْعَلْ ذَٰلِكَ فَلَيْسَ مِنَ اللَّهِ فِي شَيْءٍ إِلَّا أَنْ تَتَّقُوا مِنْهُمْ تُقَاةً ۗ وَيُحَذِّرُكُمُ اللَّهُ نَفْسَهُ ۗ وَإِلَى اللَّهِ الْمَصِيرُ
Ki awon onigbagbo ododo ma se mu awon alaigbagbo ni ore ayo leyin awon onigbagbo ododo (egbe won). Enikeni ti o ba se iyen, ko si kini kan fun un mo lodo Allahu. Afi (ti e ba mu won ni ore lori ahon) lati fi sora fun won ni ti wiwa aabo (fun igbagbo yin). Allahu n kilo ara Re fun yin. Odo Allahu si ni abo eda
قُلْ إِنْ تُخْفُوا مَا فِي صُدُورِكُمْ أَوْ تُبْدُوهُ يَعْلَمْهُ اللَّهُ ۗ وَيَعْلَمُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۗ وَاللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
So pe: “Ti e ba fi ohun ti n be ninu okan yin pamo tabi e fi han, Allahu mo on. O si mo ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan

Choose other languages: