Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #32 Translated in Yoruba

لَا يَتَّخِذِ الْمُؤْمِنُونَ الْكَافِرِينَ أَوْلِيَاءَ مِنْ دُونِ الْمُؤْمِنِينَ ۖ وَمَنْ يَفْعَلْ ذَٰلِكَ فَلَيْسَ مِنَ اللَّهِ فِي شَيْءٍ إِلَّا أَنْ تَتَّقُوا مِنْهُمْ تُقَاةً ۗ وَيُحَذِّرُكُمُ اللَّهُ نَفْسَهُ ۗ وَإِلَى اللَّهِ الْمَصِيرُ
Ki awon onigbagbo ododo ma se mu awon alaigbagbo ni ore ayo leyin awon onigbagbo ododo (egbe won). Enikeni ti o ba se iyen, ko si kini kan fun un mo lodo Allahu. Afi (ti e ba mu won ni ore lori ahon) lati fi sora fun won ni ti wiwa aabo (fun igbagbo yin). Allahu n kilo ara Re fun yin. Odo Allahu si ni abo eda
قُلْ إِنْ تُخْفُوا مَا فِي صُدُورِكُمْ أَوْ تُبْدُوهُ يَعْلَمْهُ اللَّهُ ۗ وَيَعْلَمُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۗ وَاللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
So pe: “Ti e ba fi ohun ti n be ninu okan yin pamo tabi e fi han, Allahu mo on. O si mo ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan
يَوْمَ تَجِدُ كُلُّ نَفْسٍ مَا عَمِلَتْ مِنْ خَيْرٍ مُحْضَرًا وَمَا عَمِلَتْ مِنْ سُوءٍ تَوَدُّ لَوْ أَنَّ بَيْنَهَا وَبَيْنَهُ أَمَدًا بَعِيدًا ۗ وَيُحَذِّرُكُمُ اللَّهُ نَفْسَهُ ۗ وَاللَّهُ رَءُوفٌ بِالْعِبَادِ
Ni ojo ti emi kookan yoo ri ohun ti o se ninu ise rere niwaju (re) ati ohun ti o se ninu ise ibi, o maa fe ki akoko t’o jinna wa laaarin oun ati ise ibi re. Allahu si n kilo ara Re fun yin. Allahu si ni Alaaanu awon olujosin
قُلْ إِنْ كُنْتُمْ تُحِبُّونَ اللَّهَ فَاتَّبِعُونِي يُحْبِبْكُمُ اللَّهُ وَيَغْفِرْ لَكُمْ ذُنُوبَكُمْ ۗ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَحِيمٌ
So pe: “Ti eyin ba nifee Allahu, e tele mi, Allahu maa nifee yin, O si maa fori ese yin jin yin. Allahu ni Alaforijin, Asake-orun
قُلْ أَطِيعُوا اللَّهَ وَالرَّسُولَ ۖ فَإِنْ تَوَلَّوْا فَإِنَّ اللَّهَ لَا يُحِبُّ الْكَافِرِينَ
So pe: “E tele (ti) Allahu ati Ojise. Ti e ba si peyin da, dajudaju Allahu ko nifee awon alaigbagbo

Choose other languages: