Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #193 Translated in Yoruba

وَلِلَّهِ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۗ وَاللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile. Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan
إِنَّ فِي خَلْقِ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَاخْتِلَافِ اللَّيْلِ وَالنَّهَارِ لَآيَاتٍ لِأُولِي الْأَلْبَابِ
Dajudaju awon ami wa ninu iseda awon sanmo ati ile, itelentele ati iyato oru ati osan; (ami wa ninu won) fun awon onilaakaye
الَّذِينَ يَذْكُرُونَ اللَّهَ قِيَامًا وَقُعُودًا وَعَلَىٰ جُنُوبِهِمْ وَيَتَفَكَّرُونَ فِي خَلْقِ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ رَبَّنَا مَا خَلَقْتَ هَٰذَا بَاطِلًا سُبْحَانَكَ فَقِنَا عَذَابَ النَّارِ
Awon t’o n ranti Allahu ni inaro, ijokoo ati ni idubule; ti won n ronu si iseda awon sanmo ati ile, (won si n so pe:) "Oluwa wa, Iwo ko sedaa eyi pelu iro. Mimo ni fun O. Nitori naa, so wa nibi iya Ina
رَبَّنَا إِنَّكَ مَنْ تُدْخِلِ النَّارَ فَقَدْ أَخْزَيْتَهُ ۖ وَمَا لِلظَّالِمِينَ مِنْ أَنْصَارٍ
Oluwa wa, dajudaju enikeni ti O ba mu wo inu Ina, O ti doju ti i. Ko si nii si awon oluranlowo fun awon alabosi
رَبَّنَا إِنَّنَا سَمِعْنَا مُنَادِيًا يُنَادِي لِلْإِيمَانِ أَنْ آمِنُوا بِرَبِّكُمْ فَآمَنَّا ۚ رَبَّنَا فَاغْفِرْ لَنَا ذُنُوبَنَا وَكَفِّرْ عَنَّا سَيِّئَاتِنَا وَتَوَفَّنَا مَعَ الْأَبْرَارِ
Oluwa wa, dajudaju awa gbo olupepe kan t’o n pe (ipe) si ibi igbagbo pe: "E gba Oluwa yin gbo.” A si gbagbo ni ododo. Oluwa wa, nitori naa, fori awon ese wa jin wa, ki O si pa awon asise wa re, ki O si pa wa pelu awon eni rere

Choose other languages: