Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #196 Translated in Yoruba

رَبَّنَا إِنَّكَ مَنْ تُدْخِلِ النَّارَ فَقَدْ أَخْزَيْتَهُ ۖ وَمَا لِلظَّالِمِينَ مِنْ أَنْصَارٍ
Oluwa wa, dajudaju enikeni ti O ba mu wo inu Ina, O ti doju ti i. Ko si nii si awon oluranlowo fun awon alabosi
رَبَّنَا إِنَّنَا سَمِعْنَا مُنَادِيًا يُنَادِي لِلْإِيمَانِ أَنْ آمِنُوا بِرَبِّكُمْ فَآمَنَّا ۚ رَبَّنَا فَاغْفِرْ لَنَا ذُنُوبَنَا وَكَفِّرْ عَنَّا سَيِّئَاتِنَا وَتَوَفَّنَا مَعَ الْأَبْرَارِ
Oluwa wa, dajudaju awa gbo olupepe kan t’o n pe (ipe) si ibi igbagbo pe: "E gba Oluwa yin gbo.” A si gbagbo ni ododo. Oluwa wa, nitori naa, fori awon ese wa jin wa, ki O si pa awon asise wa re, ki O si pa wa pelu awon eni rere
رَبَّنَا وَآتِنَا مَا وَعَدْتَنَا عَلَىٰ رُسُلِكَ وَلَا تُخْزِنَا يَوْمَ الْقِيَامَةِ ۗ إِنَّكَ لَا تُخْلِفُ الْمِيعَادَ
Oluwa wa, fun wa ni ohun ti O sadehun re fun wa lori (ahon) awon Ojise Re. Ma si se doju ti wa ni Ojo Ajinde. Dajudaju Iwo ki i yapa adehun
فَاسْتَجَابَ لَهُمْ رَبُّهُمْ أَنِّي لَا أُضِيعُ عَمَلَ عَامِلٍ مِنْكُمْ مِنْ ذَكَرٍ أَوْ أُنْثَىٰ ۖ بَعْضُكُمْ مِنْ بَعْضٍ ۖ فَالَّذِينَ هَاجَرُوا وَأُخْرِجُوا مِنْ دِيَارِهِمْ وَأُوذُوا فِي سَبِيلِي وَقَاتَلُوا وَقُتِلُوا لَأُكَفِّرَنَّ عَنْهُمْ سَيِّئَاتِهِمْ وَلَأُدْخِلَنَّهُمْ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ ثَوَابًا مِنْ عِنْدِ اللَّهِ ۗ وَاللَّهُ عِنْدَهُ حُسْنُ الثَّوَابِ
Oluwa won si jepe won pe: “Dajudaju Emi ko nii fi ise onise kan ninu yin rare; okunrin ni tabi obinrin, ara kan naa ni yin (nibi esan). Nitori naa, awon t’o gbe (ilu won) ju sile, ti won le jade kuro ninu ilu won, ti won si fi inira kan won nitori esin Mi, won jagun esin, won si pa won. Dajudaju Emi yoo ba won pa awon asise won re. Emi yo si mu won wo inu awon Ogba Idera ti awon odo n san ni isale re. (O je) esan lati odo Allahu. Ni odo Allahu si ni esan daadaa wa
لَا يَغُرَّنَّكَ تَقَلُّبُ الَّذِينَ كَفَرُوا فِي الْبِلَادِ
Ma se gba etan pelu igboke-gbodo awon t’o sai gbagbo ninu ilu

Choose other languages: