Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #154 Translated in Yoruba

بَلِ اللَّهُ مَوْلَاكُمْ ۖ وَهُوَ خَيْرُ النَّاصِرِينَ
Allahu si ni Alaranse yin. O si loore julo ninu awon alaranse
سَنُلْقِي فِي قُلُوبِ الَّذِينَ كَفَرُوا الرُّعْبَ بِمَا أَشْرَكُوا بِاللَّهِ مَا لَمْ يُنَزِّلْ بِهِ سُلْطَانًا ۖ وَمَأْوَاهُمُ النَّارُ ۚ وَبِئْسَ مَثْوَى الظَّالِمِينَ
A maa fi eru jeje sinu okan awon t’o sai gbagbo nitori pe won ba Allahu wa akegbe, eyi ti ko so eri kan kale fun. Ina si ni ibugbe won; ile awon alabosi si buru
وَلَقَدْ صَدَقَكُمُ اللَّهُ وَعْدَهُ إِذْ تَحُسُّونَهُمْ بِإِذْنِهِ ۖ حَتَّىٰ إِذَا فَشِلْتُمْ وَتَنَازَعْتُمْ فِي الْأَمْرِ وَعَصَيْتُمْ مِنْ بَعْدِ مَا أَرَاكُمْ مَا تُحِبُّونَ ۚ مِنْكُمْ مَنْ يُرِيدُ الدُّنْيَا وَمِنْكُمْ مَنْ يُرِيدُ الْآخِرَةَ ۚ ثُمَّ صَرَفَكُمْ عَنْهُمْ لِيَبْتَلِيَكُمْ ۖ وَلَقَدْ عَفَا عَنْكُمْ ۗ وَاللَّهُ ذُو فَضْلٍ عَلَى الْمُؤْمِنِينَ
Dajudaju Allahu ti mu adehun Re se fun yin nigba ti e n pa won pelu iyonda Re, titi di igba ti e fi sojo, ti e si n jiyan si oro. E si yapa (ase Anabi) leyin ti Allahu fi ohun ti e nifee si han yin. - O wa ninu yin eni ti n fe aye, o si n be ninu yin eni ti n fe orun. - Leyin naa, (Allahu) yi oju yin kuro ni odo won, ki O le dan yin wo. O si ti samoju kuro fun yin; Allahu ni Oloore ajulo lori awon onigbagbo ododo
إِذْ تُصْعِدُونَ وَلَا تَلْوُونَ عَلَىٰ أَحَدٍ وَالرَّسُولُ يَدْعُوكُمْ فِي أُخْرَاكُمْ فَأَثَابَكُمْ غَمًّا بِغَمٍّ لِكَيْلَا تَحْزَنُوا عَلَىٰ مَا فَاتَكُمْ وَلَا مَا أَصَابَكُمْ ۗ وَاللَّهُ خَبِيرٌ بِمَا تَعْمَلُونَ
(E ranti) nigba ti e n gunke sa lo, ti eyin ko si boju wo eni kan kan mo leyin, Ojise si n pe yin lati eyin yin. Nitori naa, (Allahu) fi ibanuje (pipa ti awon osebo pa awon kan laaarin yin) san yin ni esan ibanuje (ti e fi kan Anabi nipase aitele ase re loju ogun ’Uhd. (O ri bee) nitori ki e ma baa banuje lori ohun ti o bo fun yin ati ohun ti o sele si yin. Allahu ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise
ثُمَّ أَنْزَلَ عَلَيْكُمْ مِنْ بَعْدِ الْغَمِّ أَمَنَةً نُعَاسًا يَغْشَىٰ طَائِفَةً مِنْكُمْ ۖ وَطَائِفَةٌ قَدْ أَهَمَّتْهُمْ أَنْفُسُهُمْ يَظُنُّونَ بِاللَّهِ غَيْرَ الْحَقِّ ظَنَّ الْجَاهِلِيَّةِ ۖ يَقُولُونَ هَلْ لَنَا مِنَ الْأَمْرِ مِنْ شَيْءٍ ۗ قُلْ إِنَّ الْأَمْرَ كُلَّهُ لِلَّهِ ۗ يُخْفُونَ فِي أَنْفُسِهِمْ مَا لَا يُبْدُونَ لَكَ ۖ يَقُولُونَ لَوْ كَانَ لَنَا مِنَ الْأَمْرِ شَيْءٌ مَا قُتِلْنَا هَاهُنَا ۗ قُلْ لَوْ كُنْتُمْ فِي بُيُوتِكُمْ لَبَرَزَ الَّذِينَ كُتِبَ عَلَيْهِمُ الْقَتْلُ إِلَىٰ مَضَاجِعِهِمْ ۖ وَلِيَبْتَلِيَ اللَّهُ مَا فِي صُدُورِكُمْ وَلِيُمَحِّصَ مَا فِي قُلُوبِكُمْ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ بِذَاتِ الصُّدُورِ
Leyin naa, O so ifayabale kale fun yin leyin ibanuje; oogbe ta igun kan lo ninu yin. Igun kan ti emi ara won si ti ko ironu ba, ti won si n ni erokero si Allahu lona aito, erokero igba aimokan, won si n wi pe: “Nje a ni ase kan (ti a le mu wa) lori oro naa bi!” So pe: “Dajudaju gbogbo ase n je ti Allahu.” Won n fi pamo sinu okan won ohun ti won ko le safi han re fun o. Won n wi pe: "Ti o ba je pe a ni ase kan lori oro naa ni, won iba ti pa wa sibi." So pe: “Ti o ba je pe e wa ninu ile yin, awon ti A ti ko akoole pipa si ibujagun won mo iba kuku jade lo sibe.” (Ogun yii ri bee) nitori ki Allahu le gbidanwo ohun ti n be ninu igba-aya yin ati nitori ki O le safomo ohun ti n be ninu okan yin. Allahu si ni Onimo nipa ohun ti n be ninu igba-aya eda

Choose other languages: