Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #145 Translated in Yoruba

وَلِيُمَحِّصَ اللَّهُ الَّذِينَ آمَنُوا وَيَمْحَقَ الْكَافِرِينَ
Ati pe (o tun ri bee) nitori ki Allahu le safomo awon t’o gbagbo ni ododo ati nitori ki O le run awon alaigbagbo
أَمْ حَسِبْتُمْ أَنْ تَدْخُلُوا الْجَنَّةَ وَلَمَّا يَعْلَمِ اللَّهُ الَّذِينَ جَاهَدُوا مِنْكُمْ وَيَعْلَمَ الصَّابِرِينَ
Tabi e lero pe e maa wo inu Ogba Idera nigba ti Allahu ko ti i safi han awon t’o maa jagun (esin) ninu yin, ti ko si ti i safi han awon onisuuru
وَلَقَدْ كُنْتُمْ تَمَنَّوْنَ الْمَوْتَ مِنْ قَبْلِ أَنْ تَلْقَوْهُ فَقَدْ رَأَيْتُمُوهُ وَأَنْتُمْ تَنْظُرُونَ
Dajudaju e ti n fe iku (ogun esin) siwaju ki e to pade re. E kuku ti ri i (bayii), e si n woran
وَمَا مُحَمَّدٌ إِلَّا رَسُولٌ قَدْ خَلَتْ مِنْ قَبْلِهِ الرُّسُلُ ۚ أَفَإِنْ مَاتَ أَوْ قُتِلَ انْقَلَبْتُمْ عَلَىٰ أَعْقَابِكُمْ ۚ وَمَنْ يَنْقَلِبْ عَلَىٰ عَقِبَيْهِ فَلَنْ يَضُرَّ اللَّهَ شَيْئًا ۗ وَسَيَجْزِي اللَّهُ الشَّاكِرِينَ
Ki ni (Anabi) Muhammad bi ko se Ojise, ti awon Ojise kan ti lo siwaju re. Se ti o ba ku tabi ti won ba pa a, e maa peyin da (sesin)? Enikeni ti o ba peyin da (sesin) ko le ko inira kan kan ba Allahu. Allahu yo si san awon oludupe ni esan rere. awo eran okunbete ti won pa lose ki i se eewo fun lilo fun oso ile tabi oso ara. Iru awo eran okunbete ti won pa lose bee si di eto lati fi se bata beliti
وَمَا كَانَ لِنَفْسٍ أَنْ تَمُوتَ إِلَّا بِإِذْنِ اللَّهِ كِتَابًا مُؤَجَّلًا ۗ وَمَنْ يُرِدْ ثَوَابَ الدُّنْيَا نُؤْتِهِ مِنْهَا وَمَنْ يُرِدْ ثَوَابَ الْآخِرَةِ نُؤْتِهِ مِنْهَا ۚ وَسَنَجْزِي الشَّاكِرِينَ
Ko letoo fun emi kan lati ku afi pelu iyonda Allahu. (Iku je) akosile onigbedeke. Enikeni ti o ba n fe esan (ni) aye, A maa fun un ni aye. Enikeni ti o ba si n fe esan (ni) orun, A maa fun un ni orun. A o si san awon oludupe ni esan rere

Choose other languages: