Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #129 Translated in Yoruba

بَلَىٰ ۚ إِنْ تَصْبِرُوا وَتَتَّقُوا وَيَأْتُوكُمْ مِنْ فَوْرِهِمْ هَٰذَا يُمْدِدْكُمْ رَبُّكُمْ بِخَمْسَةِ آلَافٍ مِنَ الْمَلَائِكَةِ مُسَوِّمِينَ
Rara (o maa to wa.). Ti eyin ba se suuru, ti e si beru Allahu, ti awon (ota) ba de ba yin lojiji, Oluwa yin yoo ran yin lowo pelu egberun maarun ninu awon molaika pelu ami idanimo lara won
وَمَا جَعَلَهُ اللَّهُ إِلَّا بُشْرَىٰ لَكُمْ وَلِتَطْمَئِنَّ قُلُوبُكُمْ بِهِ ۗ وَمَا النَّصْرُ إِلَّا مِنْ عِنْدِ اللَّهِ الْعَزِيزِ الْحَكِيمِ
Allahu ko se e lasan bi ko se ki o le je iro idunnu fun yin ati nitori ki okan yin le bale pelu re. Ko si aranse lori ota (lati ibi kan kan) bi ko se lati odo Allahu, Alagbara, Ologbon
لِيَقْطَعَ طَرَفًا مِنَ الَّذِينَ كَفَرُوا أَوْ يَكْبِتَهُمْ فَيَنْقَلِبُوا خَائِبِينَ
(Allahu se aranse naa fun yin) nitori ki O le ge apa kan danu ninu awon t’o sai gbagbo, tabi nitori ki O le doju ti won, ti won si maa pada wale lofo
لَيْسَ لَكَ مِنَ الْأَمْرِ شَيْءٌ أَوْ يَتُوبَ عَلَيْهِمْ أَوْ يُعَذِّبَهُمْ فَإِنَّهُمْ ظَالِمُونَ
Ko si ohun t’o kan o ninu oro naa. Yala (Allahu) maa gba ironupiwada won tabi O maa je won niya; dajudaju alabosi ni won
وَلِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۚ يَغْفِرُ لِمَنْ يَشَاءُ وَيُعَذِّبُ مَنْ يَشَاءُ ۚ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَحِيمٌ
Ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. O n forijin eni ti O ba fe, O si n je eni ti O ba fe niya. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun

Choose other languages: