Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #131 Translated in Yoruba

لِيَقْطَعَ طَرَفًا مِنَ الَّذِينَ كَفَرُوا أَوْ يَكْبِتَهُمْ فَيَنْقَلِبُوا خَائِبِينَ
(Allahu se aranse naa fun yin) nitori ki O le ge apa kan danu ninu awon t’o sai gbagbo, tabi nitori ki O le doju ti won, ti won si maa pada wale lofo
لَيْسَ لَكَ مِنَ الْأَمْرِ شَيْءٌ أَوْ يَتُوبَ عَلَيْهِمْ أَوْ يُعَذِّبَهُمْ فَإِنَّهُمْ ظَالِمُونَ
Ko si ohun t’o kan o ninu oro naa. Yala (Allahu) maa gba ironupiwada won tabi O maa je won niya; dajudaju alabosi ni won
وَلِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۚ يَغْفِرُ لِمَنْ يَشَاءُ وَيُعَذِّبُ مَنْ يَشَاءُ ۚ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَحِيمٌ
Ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. O n forijin eni ti O ba fe, O si n je eni ti O ba fe niya. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَأْكُلُوا الرِّبَا أَضْعَافًا مُضَاعَفَةً ۖ وَاتَّقُوا اللَّهَ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ
Eyin onigbagbo ododo, e ma se je ele, adipele lori adipele. Ki e si beru Allahu nitori ki e le jere
وَاتَّقُوا النَّارَ الَّتِي أُعِدَّتْ لِلْكَافِرِينَ
Ki e si sora fun Ina ti Won ti pa lese sile de awon alaigbagbo

Choose other languages: