Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #112 Translated in Yoruba

تِلْكَ آيَاتُ اللَّهِ نَتْلُوهَا عَلَيْكَ بِالْحَقِّ ۗ وَمَا اللَّهُ يُرِيدُ ظُلْمًا لِلْعَالَمِينَ
Iwonyi ni awon ayah Allahu, ti A n ke e fun o pelu ododo. Allahu ko si gbero abosi kan si gbogbo eda
وَلِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۚ وَإِلَى اللَّهِ تُرْجَعُ الْأُمُورُ
Ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Odo Allahu si ni won maa seri awon oro eda pada si
كُنْتُمْ خَيْرَ أُمَّةٍ أُخْرِجَتْ لِلنَّاسِ تَأْمُرُونَ بِالْمَعْرُوفِ وَتَنْهَوْنَ عَنِ الْمُنْكَرِ وَتُؤْمِنُونَ بِاللَّهِ ۗ وَلَوْ آمَنَ أَهْلُ الْكِتَابِ لَكَانَ خَيْرًا لَهُمْ ۚ مِنْهُمُ الْمُؤْمِنُونَ وَأَكْثَرُهُمُ الْفَاسِقُونَ
E je ijo t’o loore julo, ti A gbe dide fun awon eniyan; e n pase ohun rere, e n ko ohun buruku, e si gbagbo ninu Allahu. Ti o ba je pe awon ahlul-kitab gbagbo lododo ni, iba loore julo fun won. Onigbagbo ododo wa ninu won , opolopo won si ni obileje
لَنْ يَضُرُّوكُمْ إِلَّا أَذًى ۖ وَإِنْ يُقَاتِلُوكُمْ يُوَلُّوكُمُ الْأَدْبَارَ ثُمَّ لَا يُنْصَرُونَ
Won ko nii ko inira ba yin ayafi ipalara die. Ti won ba si ba yin ja, won a sa fun yin. Leyin naa, A o nii ran won lowo
ضُرِبَتْ عَلَيْهِمُ الذِّلَّةُ أَيْنَ مَا ثُقِفُوا إِلَّا بِحَبْلٍ مِنَ اللَّهِ وَحَبْلٍ مِنَ النَّاسِ وَبَاءُوا بِغَضَبٍ مِنَ اللَّهِ وَضُرِبَتْ عَلَيْهِمُ الْمَسْكَنَةُ ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ كَانُوا يَكْفُرُونَ بِآيَاتِ اللَّهِ وَيَقْتُلُونَ الْأَنْبِيَاءَ بِغَيْرِ حَقٍّ ۚ ذَٰلِكَ بِمَا عَصَوْا وَكَانُوا يَعْتَدُونَ
Abuku yoo maa ba won nibikibi ti owo awon (musulumi) ba ti ba won afi (ti won ba n be) pelu aabo lati odo Allahu (iyen ni pe, ki won gba ’Islam) ati aabo lati odo awon eniyan (iyen ni pe, ki won gba lati maa san owo isakole fun ijoba ’Islam). Won seri pada pelu ibinu lati odo Allahu. Won si ko osi ba won. Iyen nitori pe, dajudaju won sai gbagbo ninu awon ayah Allahu, won tun n pa awon Anabi lai letoo. Iyen nitori pe, won yapa (ase Allahu), won si n tayo enu ala

Choose other languages: