Quran Apps in many lanuages:

Surah Yusuf Ayahs #50 Translated in Yoruba

يُوسُفُ أَيُّهَا الصِّدِّيقُ أَفْتِنَا فِي سَبْعِ بَقَرَاتٍ سِمَانٍ يَأْكُلُهُنَّ سَبْعٌ عِجَافٌ وَسَبْعِ سُنْبُلَاتٍ خُضْرٍ وَأُخَرَ يَابِسَاتٍ لَعَلِّي أَرْجِعُ إِلَى النَّاسِ لَعَلَّهُمْ يَعْلَمُونَ
Yusuf, iwo olododo, fun wa ni alaye itumo ala (yii): maalu meje t’o sanra. Awon maalu meje t’o ru si n je won. Ati siri meje tutu ati omiran gbigbe. (Ki ni itumo re) nitori ki ng le fi abo sodo awon eniyan ati nitori ki won le mo (itumo re)
قَالَ تَزْرَعُونَ سَبْعَ سِنِينَ دَأَبًا فَمَا حَصَدْتُمْ فَذَرُوهُ فِي سُنْبُلِهِ إِلَّا قَلِيلًا مِمَّا تَأْكُلُونَ
O so pe: “Eyin yoo gbin nnkan ogbin fun odun meje gbako (gege bi) ise (yin). Ohunkohun ti e ba ko lere oko, ki e fi sile sinu siri re afi die ti e maa je ninu re
ثُمَّ يَأْتِي مِنْ بَعْدِ ذَٰلِكَ سَبْعٌ شِدَادٌ يَأْكُلْنَ مَا قَدَّمْتُمْ لَهُنَّ إِلَّا قَلِيلًا مِمَّا تُحْصِنُونَ
Leyin naa, odun meje t’o le (fun oda ojo) yoo de leyin iyen, (awon ara ilu) yo si le je ohun ti e ti (ko lere oko) siwaju afi die ti e maa fi pamo (fun gbigbin)
ثُمَّ يَأْتِي مِنْ بَعْدِ ذَٰلِكَ عَامٌ فِيهِ يُغَاثُ النَّاسُ وَفِيهِ يَعْصِرُونَ
Leyin naa, odun kan ti Won yoo rojo fun awon eniyan yoo de leyin iyen. Awon eniyan yo si maa fun eso ati wara mu ninu odun naa
وَقَالَ الْمَلِكُ ائْتُونِي بِهِ ۖ فَلَمَّا جَاءَهُ الرَّسُولُ قَالَ ارْجِعْ إِلَىٰ رَبِّكَ فَاسْأَلْهُ مَا بَالُ النِّسْوَةِ اللَّاتِي قَطَّعْنَ أَيْدِيَهُنَّ ۚ إِنَّ رَبِّي بِكَيْدِهِنَّ عَلِيمٌ
Oba so pe: “E mu (Yusuf) wa fun mi.” Nigba ti iranse naa de odo re. (Yusuf) so pe: “Pada sodo oga re, ki o bi i leere pe, ki ni o sele si awon obinrin ti won re owo ara won. Dajudaju Oluwa mi ni Onimo nipa ete won.”

Choose other languages: