Quran Apps in many lanuages:

Surah Yunus Ayahs #70 Translated in Yoruba

أَلَا إِنَّ لِلَّهِ مَنْ فِي السَّمَاوَاتِ وَمَنْ فِي الْأَرْضِ ۗ وَمَا يَتَّبِعُ الَّذِينَ يَدْعُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ شُرَكَاءَ ۚ إِنْ يَتَّبِعُونَ إِلَّا الظَّنَّ وَإِنْ هُمْ إِلَّا يَخْرُصُونَ
Gbo, dajudaju ti Allahu ni enikeni t’o n be ninu awon sanmo ati enikeni t’o n be lori ile. Ki ni awon t’o n pe awon orisa leyin Allahu n tele na? Won ko tele (kini kan) bi ko se aroso. Won ko si se kini kan bi ko se pe won n paro
هُوَ الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ اللَّيْلَ لِتَسْكُنُوا فِيهِ وَالنَّهَارَ مُبْصِرًا ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يَسْمَعُونَ
Oun ni Eni t’O se oru fun yin nitori ki e le sinmi ninu re. (O se) osan ni (asiko) ti e oo riran (kedere). Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o n gboro (ododo)
قَالُوا اتَّخَذَ اللَّهُ وَلَدًا ۗ سُبْحَانَهُ ۖ هُوَ الْغَنِيُّ ۖ لَهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۚ إِنْ عِنْدَكُمْ مِنْ سُلْطَانٍ بِهَٰذَا ۚ أَتَقُولُونَ عَلَى اللَّهِ مَا لَا تَعْلَمُونَ
Won wi pe: “Allahu so eda di omo.” - Mimo ni fun Un. Oun ni Oluroro. TiRe ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. – Ko si eri kan lodo yin fun eyi. Se e fe safiti ohun ti e o nimo nipa re sodo Allahu ni
قُلْ إِنَّ الَّذِينَ يَفْتَرُونَ عَلَى اللَّهِ الْكَذِبَ لَا يُفْلِحُونَ
So pe: “Dajudaju awon t’o n da adapa iro mo Allahu, won ko nii jere.”
مَتَاعٌ فِي الدُّنْيَا ثُمَّ إِلَيْنَا مَرْجِعُهُمْ ثُمَّ نُذِيقُهُمُ الْعَذَابَ الشَّدِيدَ بِمَا كَانُوا يَكْفُرُونَ
Igbadun bin-intin (le wa fun won) nile aye. Leyin naa, odo Wa ni ibupadasi won. Leyin naa, A oo fun won ni iya lile to wo nitori pe won n sai gbagbo

Choose other languages: