Quran Apps in many lanuages:

Surah Ta-Ha Ayahs #90 Translated in Yoruba

فَرَجَعَ مُوسَىٰ إِلَىٰ قَوْمِهِ غَضْبَانَ أَسِفًا ۚ قَالَ يَا قَوْمِ أَلَمْ يَعِدْكُمْ رَبُّكُمْ وَعْدًا حَسَنًا ۚ أَفَطَالَ عَلَيْكُمُ الْعَهْدُ أَمْ أَرَدْتُمْ أَنْ يَحِلَّ عَلَيْكُمْ غَضَبٌ مِنْ رَبِّكُمْ فَأَخْلَفْتُمْ مَوْعِدِي
(Anabi) Musa si pada sodo ijo re pelu ibinu ati ibanuje. O so pe: "Eyin ijo mi, se Oluwa yin ko ti ba yin se adehun daadaa ni? Se adehun ti pe ju loju yin ni tabi e fe ki ibinu ko le yin lori lati odo Oluwa yin ni e fi yapa adehun mi
قَالُوا مَا أَخْلَفْنَا مَوْعِدَكَ بِمَلْكِنَا وَلَٰكِنَّا حُمِّلْنَا أَوْزَارًا مِنْ زِينَةِ الْقَوْمِ فَقَذَفْنَاهَا فَكَذَٰلِكَ أَلْقَى السَّامِرِيُّ
Won wi pe: “Awa ko finnufindo yapa adehun funra wa, sugbon won di eru oso awon eniyan (Misro) ru wa lorun. A si ju u sinu ina (pelu ase Samiriyy). Bayen naa si ni Samiriyy se ju tire.”
فَأَخْرَجَ لَهُمْ عِجْلًا جَسَدًا لَهُ خُوَارٌ فَقَالُوا هَٰذَا إِلَٰهُكُمْ وَإِلَٰهُ مُوسَىٰ فَنَسِيَ
O si (fi mo) omo maalu oborogidi kan jade fun won, t’o n dun (bii maalu). Won si wi pe: "Eyi ni olohun yin ati olohun Musa. Amo o ti gbagbe (re)
أَفَلَا يَرَوْنَ أَلَّا يَرْجِعُ إِلَيْهِمْ قَوْلًا وَلَا يَمْلِكُ لَهُمْ ضَرًّا وَلَا نَفْعًا
Se won ko ri i pe ko le da esi oro kan pada fun won ni, ko si ni agbara lati ko inira tabi anfaani kan ba won
وَلَقَدْ قَالَ لَهُمْ هَارُونُ مِنْ قَبْلُ يَا قَوْمِ إِنَّمَا فُتِنْتُمْ بِهِ ۖ وَإِنَّ رَبَّكُمُ الرَّحْمَٰنُ فَاتَّبِعُونِي وَأَطِيعُوا أَمْرِي
Ati pe dajudaju Harun ti so fun won siwaju pe: “Eyin ijo mi, won kan fi se adanwo fun yin ni. Dajudaju Oluwa yin ni Ajoke-aye. Nitori naa, e tele mi. Ki e si tele ase mi.”

Choose other languages: