Quran Apps in many lanuages:

Surah Sad Ayahs #24 Translated in Yoruba

وَشَدَدْنَا مُلْكَهُ وَآتَيْنَاهُ الْحِكْمَةَ وَفَصْلَ الْخِطَابِ
Ati pe A fun ijoba re ni agbara. A si fun un ni ipo Anabi ati eko oro ati idajo
وَهَلْ أَتَاكَ نَبَأُ الْخَصْمِ إِذْ تَسَوَّرُوا الْمِحْرَابَ
Nje iro awon onija ti de odo re; nigba ti won pon ogiri ile ijosin
إِذْ دَخَلُوا عَلَىٰ دَاوُودَ فَفَزِعَ مِنْهُمْ ۖ قَالُوا لَا تَخَفْ ۖ خَصْمَانِ بَغَىٰ بَعْضُنَا عَلَىٰ بَعْضٍ فَاحْكُمْ بَيْنَنَا بِالْحَقِّ وَلَا تُشْطِطْ وَاهْدِنَا إِلَىٰ سَوَاءِ الصِّرَاطِ
Nigba ti won wole to (Anabi) Dawud, eru ba a lati ara won. Won so pe: "Ma se beru. Onija meji (ni wa). Apa kan wa tayo enu-ala si apa kan. Nitori naa, dajo laaarin wa pelu ododo. Ma sabosi. Ki o si to wa si ona taara
إِنَّ هَٰذَا أَخِي لَهُ تِسْعٌ وَتِسْعُونَ نَعْجَةً وَلِيَ نَعْجَةٌ وَاحِدَةٌ فَقَالَ أَكْفِلْنِيهَا وَعَزَّنِي فِي الْخِطَابِ
Dajudaju eyi ni arakunrin mi. O ni abo ewure mokandin-logorun-un. Emi si ni abo ewure eyo kan. O si so pe: "Fa a le mi lowo. O si bori mi ninu oro
قَالَ لَقَدْ ظَلَمَكَ بِسُؤَالِ نَعْجَتِكَ إِلَىٰ نِعَاجِهِ ۖ وَإِنَّ كَثِيرًا مِنَ الْخُلَطَاءِ لَيَبْغِي بَعْضُهُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ إِلَّا الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ وَقَلِيلٌ مَا هُمْ ۗ وَظَنَّ دَاوُودُ أَنَّمَا فَتَنَّاهُ فَاسْتَغْفَرَ رَبَّهُ وَخَرَّ رَاكِعًا وَأَنَابَ ۩
(Anabi Dawud) so pe: "O ti sabosi si o nipa bibeere abo ewure tire mo awon abo ewure tire. Dajudaju opolopo ninu awon olubada-nnkanpo, apa kan won maa n tayo enu-ala lori apa kan afi awon t’o ba gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere. Die si ni won. (Anabi) Dawud si mo daju pe A kan fi (ibeere naa) sadanwo fun oun ni. Nitori naa, o toro aforijin lodo Oluwa re (nipa aiteti gbo oro lenu eni- afesunkan). O doju bole lati fori kanle. O si ronu piwada (sodo Allahu). onka iyawo won le po ni onka ki i se ni ti igbadun adun-ara bi ko se pe Allahu (subhanahu wa ta’ala) fe ko Anabi Dawud (’alaehi-ssolatu wa-ssalam) ni eko igbejo nitori pe Allahu (subhanahu wa ta’ala) fe fi se adajo laaarin awon ijo re. Aiteti gbo oro lenu eni-afesunkan ni asise t’o sele si Anabi Dawud (’alaehi-ssolatu wa-ssalam). Eyi naa si ni ohun ti o toro aforijin Olohun fun

Choose other languages: