Quran Apps in many lanuages:

Surah Saba Ayahs #33 Translated in Yoruba

وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا الْوَعْدُ إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ
Won si n wi pe: “Igba wo ni adehun yii yoo se ti e ba je olododo?”
قُلْ لَكُمْ مِيعَادُ يَوْمٍ لَا تَسْتَأْخِرُونَ عَنْهُ سَاعَةً وَلَا تَسْتَقْدِمُونَ
So pe: “Adehun ojo kan n be fun yin, ti eyin ko le sun siwaju di igba kan, e o si le fa a seyin.”
وَقَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا لَنْ نُؤْمِنَ بِهَٰذَا الْقُرْآنِ وَلَا بِالَّذِي بَيْنَ يَدَيْهِ ۗ وَلَوْ تَرَىٰ إِذِ الظَّالِمُونَ مَوْقُوفُونَ عِنْدَ رَبِّهِمْ يَرْجِعُ بَعْضُهُمْ إِلَىٰ بَعْضٍ الْقَوْلَ يَقُولُ الَّذِينَ اسْتُضْعِفُوا لِلَّذِينَ اسْتَكْبَرُوا لَوْلَا أَنْتُمْ لَكُنَّا مُؤْمِنِينَ
Awon t’o sai gbagbo wi pe: “A o nii ni igbagbo ninu al-Ƙur’an yii ati eyi t’o wa siwaju re.” Ti o ba je pe o ba ri won ni nigba ti won ba da awon alabosi duro niwaju Oluwa won, (o maa ri won ti) apa kan won yoo da oro naa pada si apa kan; awon ti won so di ole (ninu won) yoo wi fun awon t’o segberaga (ninu won) pe: “Ti ki i ba se eyin ni, awa iba je onigbagbo ododo.”
قَالَ الَّذِينَ اسْتَكْبَرُوا لِلَّذِينَ اسْتُضْعِفُوا أَنَحْنُ صَدَدْنَاكُمْ عَنِ الْهُدَىٰ بَعْدَ إِذْ جَاءَكُمْ ۖ بَلْ كُنْتُمْ مُجْرِمِينَ
Awon t’o segberaga yo si wi fun awon ti won so di ole pe: “Se awa l’a se yin lori kuro ninu imona leyin ti o de ba yin? Rara o! Odaran ni yin ni.”
وَقَالَ الَّذِينَ اسْتُضْعِفُوا لِلَّذِينَ اسْتَكْبَرُوا بَلْ مَكْرُ اللَّيْلِ وَالنَّهَارِ إِذْ تَأْمُرُونَنَا أَنْ نَكْفُرَ بِاللَّهِ وَنَجْعَلَ لَهُ أَنْدَادًا ۚ وَأَسَرُّوا النَّدَامَةَ لَمَّا رَأَوُا الْعَذَابَ وَجَعَلْنَا الْأَغْلَالَ فِي أَعْنَاقِ الَّذِينَ كَفَرُوا ۚ هَلْ يُجْزَوْنَ إِلَّا مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ
Awon ti won so di ole yo si wi fun awon t’o segberaga pe: “Rara! Ete oru ati osan (lati odo yin loko ba wa) nigba ti e n pa wa ni ase pe ki a sai gbagbo ninu Allahu, ki a si so (awon kan) di egbe Re.” Won fi abamo won pamo nigba ti won ri iya. A si ko ewon si orun awon t’o sai gbagbo. Se A oo san won ni esan kan bi ko se ohun ti won n se nise

Choose other languages: