Quran Apps in many lanuages:

Surah Luqman Ayahs #22 Translated in Yoruba

وَلَا تُصَعِّرْ خَدَّكَ لِلنَّاسِ وَلَا تَمْشِ فِي الْأَرْضِ مَرَحًا ۖ إِنَّ اللَّهَ لَا يُحِبُّ كُلَّ مُخْتَالٍ فَخُورٍ
Ma se ko parike re si eniyan. Ma si se rin lori ile pelu faari. Dajudaju Allahu ko feran gbogbo onigbeeraga, onifaari
وَاقْصِدْ فِي مَشْيِكَ وَاغْضُضْ مِنْ صَوْتِكَ ۚ إِنَّ أَنْكَرَ الْأَصْوَاتِ لَصَوْتُ الْحَمِيرِ
Je ki irin ese re wa ni iwontun-wonsi, ki o si re ohun re nile. Dajudaju ohun t’o buru julo ma ni ohun ketekete.”
أَلَمْ تَرَوْا أَنَّ اللَّهَ سَخَّرَ لَكُمْ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ وَأَسْبَغَ عَلَيْكُمْ نِعَمَهُ ظَاهِرَةً وَبَاطِنَةً ۗ وَمِنَ النَّاسِ مَنْ يُجَادِلُ فِي اللَّهِ بِغَيْرِ عِلْمٍ وَلَا هُدًى وَلَا كِتَابٍ مُنِيرٍ
Se e o ri i pe dajudaju Allahu ro ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile fun yin, O si pe awon ike Re fun yin ni gbangba ati ni koro? O si wa ninu awon eniyan eni t’o n jiyan nipa Allahu lai ni imo (al-Ƙur’an) ati imona (ninu sunnah Anabi s.a.w.) ati tira (onimo-esin) t’o n tan imole (si oro esin)
وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ اتَّبِعُوا مَا أَنْزَلَ اللَّهُ قَالُوا بَلْ نَتَّبِعُ مَا وَجَدْنَا عَلَيْهِ آبَاءَنَا ۚ أَوَلَوْ كَانَ الشَّيْطَانُ يَدْعُوهُمْ إِلَىٰ عَذَابِ السَّعِيرِ
Nigba ti won ba si so fun won pe: “E tele ohun ti Allahu sokale.” Won a wi pe: “Rara! A maa tele ohun ti a ba lowo awon baba wa ni.” (Se won yoo tele awon baba won) t’ohun ti bi Esu se n pe won sibi iya Ina t’o n jo fofo
وَمَنْ يُسْلِمْ وَجْهَهُ إِلَى اللَّهِ وَهُوَ مُحْسِنٌ فَقَدِ اسْتَمْسَكَ بِالْعُرْوَةِ الْوُثْقَىٰ ۗ وَإِلَى اللَّهِ عَاقِبَةُ الْأُمُورِ
Enikeni ti o ba jura re sile fun Allahu, ti o je oluse-rere, dajudaju onitoun ti diro mo okun t’o fokan bale julo. Ati pe odo Allahu ni ikangun awon oro (eda)

Choose other languages: